NAFDAC ti awọn ileeṣẹ burẹẹdi ati ti piọ-wọta ti ko niwee ijọba  pa

Adewale Adeoye

Ajọ to n ri sohun jijẹ ati mimu lorileede wa, NAFDAC, ẹka ipinlẹ Rivers, ti ti awọn ileeṣẹ burẹdi mẹwaa ati ileeṣẹ piọ-wọta mẹjọ pa patapata, nitori pe wọn ko tẹle aṣẹ ati ilana ijọba ipinlẹ naa. Lara ẹsun ti NAFDAC fi kan awọn alaṣẹ ileeṣẹ ti wọn ti pa naa ni pe awọn ileeṣẹ kọọkan lara awọn ti wọn n ti yii n ṣe awọn ohun ti ẹnu n jẹ layiika ti ko mọ rara, awọn mi-in ninu wọn n lo ayederu orukọ, iyẹn labẹẹli lati fi maa taja wọn lai gbaṣẹ lọwọ ijọba, tawọn mi-in ko si niwee aṣẹ lati maa ṣiṣẹ ti wọn n ṣe.

ALAROYE gbọ pe ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni awọn alaṣẹ ajọ yii n lọ kaakiri igberiko ipinlẹ Rivers, ti wọn si fọwọ ofin mu awọn alaṣẹ ileeṣẹ ti wọn ko kunju oṣuwọn tabi ti wọn tapa sofin ijọba orileede Nigeria ati ti ipinlẹ Rivers ni gbogbo ọna.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, lọ bayii pe, ‘Lẹyin iwadii ta a ṣe nipa awọn ileeṣẹ burẹẹdi kan atawọn ileeṣẹ to n ṣe omi laarin ilu, ẹri wa pe awọn ileeṣẹ burẹẹdi mẹwaa ati ileeṣẹ omi mẹjọ kan ko kunju oṣuwọn to laarin ilu. Awọn kan laarin wọn ko niwee ijọba lọwọ, awọn kan n lo labẹẹli awọn ileeṣẹ mi-in, awọn kan n ṣe awọn ọja wọn layiika ti ko mọ, awọn kan n lo ayederu iwe aṣẹ ijọba, nigba tawọn kan kuro lagbegbe ti wọn forukọ rẹ silẹ lọdọ ijọba, ti wọn ko si sọ fawọn alaṣẹ ijọba pe awọn ti paarọ ọfiisi. Gbogbo ẹsun ta a fi kan awọn ileeṣẹ naa ni ko ba ofin mu, idi ree ta a ṣe waa tilẹkun ileeṣẹ wọn pa patapata bayii.

NAFDAC waa gba awọn alaṣẹ ileeṣẹ ti wọn ti pa ọhun nimọran pe ki wọn ṣe ohun gbogbo lasiko, ki wọn baa le ṣi awọn ileeṣẹ wọn ti wọn ti pa, ki wọn le maa ba iṣẹ wọn lọ.

 

 

Leave a Reply