Ileeṣẹ ologun ṣafihan awọn Boko Haram to le lọọọdunrun ti wọn lawọn sọrẹnda

Faith Adebọla

Oriṣiiriṣii akọle lawọn agbebọn atawọn afẹmiṣofo Boko Haram kan ti wọn sọrẹnda fawọn ọmoogun ilẹ niluu niluu Bama, lagbegbe ijọba ibilẹ Bama, ipinlẹ Borno, gbe dani, lati fihan pe awọn ti ronupiwada, awọn si tọrọ aforiji lọwọ gbogbo ọmọ Naijiria, wọn lawọn tuuba, ki wọn dariji awọn.

Alukoro ileeṣẹ ologun, Ọgagun Onyema Nwachukwu, sọ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aje, Mọnde yii, nipa iṣẹlẹ ọhun pe, ojilelọọọdunrun o din marun-un (335) awọn jagunjagun afẹmiṣofo, ati okoolelẹẹẹdẹgbẹrin ati mẹfa (746) awọn iyawo, ọmọ, atawọn mọlẹbi wọn gbogbo, titi kan ọkan lara awọn ọmọbinrin ileewe Chibok ti wọn ji gbe nijọsi lo wa lara awọn ti wọn wa lakata awọn ṣọja ilẹ wa ọhun, ti wọn lawọn ti sọrẹnda nidii iwa afẹmiṣofo ti wọn n ṣe tẹlẹ.

Lara akọle ti wọn gbe dani naa ka pe: “Ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ jọọ, ẹ foriji wa,” “Ibugbe alaafia ni ipinlẹ Borno o,” “A o fẹmi ṣofo mọ, alaafia la fẹ,” ati bẹẹ bẹẹ lọ, wọn si fi ede Hausa ati Fulani ko awọn akọle mi-in.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, ni wọn ni mọkanlelogun lara awọn ‘mi o ja mọ’ afẹmiṣofo naa tuuba fawọn ọga ṣọja ni ibudo awọn ologun to wa niluu Bama, ti wọn si darapọ mọ awọn ẹlẹgbẹ wọn to ti sọrẹnda ṣaaju nibudo naa. Ọgagun Abdulwahab Adelokun Adetayọ lo gba wọn wọle.

Lasiko afihan naa, Ọgagun Eyitayọ sọ pe igbesẹ to daa ni wọn gbe lati sọrẹnda, ti wọn si ko awọn nnkan ija wọn loriṣiiriṣii silẹ, o si rọ wọn lati ba awọn ẹlẹgbẹ wọn to wa ninu igbo sọrọ, pe kawọn naa gbe igbesẹ alaafia bii eyi.

Eyitayọ ni awọn o ni i tu awọn abọde ogun yii silẹ saarin ilu bẹẹ o, wọn ṣi maa wa nikaawọ ileeṣẹ ologun na, awọn maa fun wọn ni oriṣiiriṣii idalẹkọọ ati ayẹwo, awọn si maa mojuto wọn lati ri i pe ironu wọn, igbe-aye wọn, ati iwa wọn ti kuro ni ti afẹmiṣofo, wọn o si le di ewu faraalu mọ.

Leave a Reply