Ileeṣẹ ọlọpaa binu si ọkan ninu wọn to gbe baagi fun iyawo Atiku

Mosunmọla Saka

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede yii ti koro oju si iwa ti ọlọpaa obinrin kan hu gẹgẹ bo ṣe gbagbe iṣẹ to n jẹ fun orilẹ-ede yii, to si sọ ara ẹ di ọmọ ọdọ ojiji fun Titi Abubakar, iyawo oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, lasiko to gbe baagi iyawo Atiku dani, to si sun mọ ọn gbagbaagba bii pe yoo pọn si i lẹyin nibi eto igbimọ awọn obinrin ti Titi Abubakar ṣagbekalẹ rẹ niluu Abuja L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii.

Awọn ọmọ Naijiria lori ẹrọ ayelujara ko dakẹ ọrọ ibinu ati ẹfẹ ni sisọ latigba ti wọn ti ri fọto obinrin ọlọpaa ọhun lori ẹrọ ayelujara Twitter, ti oludije dupo aarẹ ọhun gbe e si, nibẹ lo ti gbe baagi madaamu rẹ bii pe iṣẹ ti wọn kanlẹ gba a fun ni. Wọn ni iwa arifin ni nnkan ti obinrin ọlọpaa naa ati Titi Abubakar hu si ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Naijiria. Awọn kan tilẹ sọ pe ohun to maa ṣẹlẹ lẹyin ti Atiku ba wọle ibo aarẹ ni wọn fi n han wa diẹdiẹ yẹn tori ẹni to le ran odidi ọlọpaa niru iṣẹ yii, awa araalu lasan o ni ja mọ nnkan kan loju wọn niyẹn.

Nigba to n sọrọ lori fọto to mu ki awọn ọmọ Naijiria lori ẹrọ ayelujara maa binu sọrọ ọhun, Olumuyiwa Adejọbi to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ yii loun ko kuku ri iyawo Atiku ba wi bi ki i ṣe ti ojugba oun ti okobo rẹ o bọ ohun ti wọn ni ko bọ. O ṣeleri pe oun yoo ri i daju pe wọn wa obinrin naa kan, yoo si jẹ iya to tọ si i.

Adejọbi ni iwa radarada gbaa ati ailojuti ni fun ọlọpaa to wa lẹnu iṣẹ ẹ lati maa gbe baagi ọga to tẹle jade, o ni iru iwa yii o ni i jẹ ko ṣe ojuṣe ẹ daadaa gẹgẹ bii agbofinro, ati wi pe oun o ni i faaye gba iru iwa yii lati tẹsiwaju nileeṣẹ ọlọpaa, nitori erongba awọn agbofinro ni lati ṣe atunto sawọn kudiẹ kudiẹ to wa ninu ilu.

O ni, “A o le faaye gba iru iwa yii rara. A ti tẹsẹ bọ iwadii lori ba a ṣe maa wa obinrin naa jade, koda to ba wọ inu iho eera. Si awa oṣiṣẹ ọlọpaa, iwa ti ko bojumu rara ni, a o si ni i gba ko maa lọ bo ṣe ti n lọ yii.

Leave a Reply