Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti ni kọmiṣanna tuntun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Wọn ti gbe kọmisanna tuntun wa fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun. Orukọ rẹ ni CP Olokode Ọlawale (Psc), oun lo gbapo lọwọ Kọmisanna tẹlẹ, Udie J. Adie, ti wọn ti gbe kuro l’Ọṣun bayii.

Ọmọ bibi ijọba ibilẹ Ọdẹda, nipinlẹ Ogun, ni Olokode, ọdun 1988 lo si darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa gẹgẹ bii Cadet ASP.

O ti ṣiṣẹ ri lawọn ipinlẹ bii Ogun, Lagos, Ọyọ, Ọṣun, Niger, Cross River, Kogi, Kano, Jigawa, Abuja ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oun lo wa ni ẹnuboode ilẹ wa (Border Patrol) ki wọn to gbe e wa sipinlẹ Ọṣun loṣu kejila, ti a wa yii.

Leave a Reply