Ileya: Ijọba Kwara fagi le ipejọpọ Yidi, ṣiṣi ile itaja atawọn ibudo igbafẹ lasiko ọdun

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Lati dẹkun atankalẹ arun Koronafairọọsi nipinlẹ Kwara, ijọba ti fagi le ipejọpọ ni Yidi lọdun yii. Bakan naa lawọn ile itaja nla bii Shoprite atawọn mi-in ko gbọdọ ṣilẹkun. Igbimọ to n gbogun ti arun Covid-19 ti Igbakeji Gomina, Kayọde Alabi, n dari lo kede ọrọ naa nibi ipade awọn oniroyin to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii. Wọn ni nitori bi ero ṣe maa n pọ ni Eid nijọba fi gbe igbesẹ naa pẹlu ajọmọ igbimọ to n ṣakoso ẹsin Musulumi niluu Ilọrin.

Alabi ni awọn ile itaja nla bii Shoprite ati ibudo igbafẹ bii ibudo ti wọn ko awọn ẹranko si, Unilọrin Zoological Garden, tawọn eeyan maa n rọ lọ lasiko ọdun maa wa ni titi lọjọ Ileya ati lọjọ keji.

O ni eto adura Jumat ṣi wa bo ṣe wa, ṣugbọn awọn to ba lọọ jọsin gbọdọ tẹle gbogbo ilana tijọba ti la kalẹ, lara rẹ ni lilo ibomu ati titakete si ara.

Bakan naa, ijọba ti tun fofin de iṣọ-oru lawọn ṣọọṣi, bẹẹ ni eto isin ọjọ isinmi ko gbọdọ ju wakati meji lọ. O tun ni gbogbo ile ọti, ile-ijo ati bẹẹ lọ gbọdọ wa ni titi. Awọn ero nibi ayẹyẹ igbeyawo tabi wẹjẹ-wẹmu kan ko gbọdọ ju aadọta lọ.

O fi kun un pe awọn awakọ takiisi igboro ko gbọdọ gbe ju eeyan meji sẹyin ati ẹni kan niwaju, gbogbo wọn lo si gbọdọ lo ibomu. Ọlọkada naa ko lanfaani lati gbe ju eeyan kan ṣoṣo lọ.

Ijọba ti waa ni ẹni to ba tapa sofin ti wọn ti la kalẹ yii yoo rugi oyin.

 

Leave a Reply