Ilu kọ ọba Ọlọta ti Odo-Ọwa, ni Kwara, wọn ni dandan ni ko fipo silẹ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Awọn olugbe ilu Odo-Ọwa, nijọba ibilẹ Oke-Ẹrọ, nipinlẹ Kwara, awọn iwarẹfa (afọbajẹ) ati awọn ọmọ aafin ni wọn ti kọwe kan fẹrẹgẹdẹ si Gomina ipinlẹ naa, Abdulrahman Abdulrazaq, ti wọn n pe fun yiyọ ọba wọn, Ọlọta tilu Odo-Ọwa, Ọba Joshua Adẹyẹmi Adimula, nipo fẹsun pe ko bọwọ fun ofin, aṣa ilu ati awọn ẹsun miiran.
Ninu iwe kan ti wọn kọ si Gomina Abdulrazaq ni ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2022, eyi ti ẹgbẹ awọn ọmọ ọba buwọ lu ni wọn ti sọ pe lẹyin ọpọlọpọ ipade ti ilu, awọn afọbajẹ ati awọn ọmọ ọba ṣe, wọn ti fẹnu ko pe ki alaafia le jọba niluu Odo-Ọwa ati ijọba ibilẹ Oke-Ẹrọ lapapọ, dandan ni ki Ọlọta Odo-Ọwa, Ọba Joshua Adẹyẹmi Adimula, fi apere silẹ, ki gomina si buwọ lu iyọnipo rẹ kiakia.
Oniruuru ni awọn ẹsun ti wọn ka si Kabiyesi lẹsẹ, wọn ni ọba to yẹ ko tolu lo n lọwọ ninu dida ilu ru. Wọn tẹsiwaju pe iwa eeri, iwa adojutini kun ọwọ Kabiyesi ati awọn oloye rẹ, ti ilu ko si ni idagbasoke rara to mu ki ilu pin yẹlẹ-yẹlẹ bayii, ti eku ko si ke bii eku, ẹyẹ o ke bii ẹyẹ mọ, fun idi eyi, afi ki gomina rọ ọ loye ni alaafia too le jọba niluu Odo-Ọwa, ati ijọba ibilẹ Oke-Ẹrọ lapapọ.
Ninu iwe kan ti wọn ti kọkọ kọ ṣaaju si kọmiṣanna to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Kwara, ni wọn ti ka oniruu ẹsun ọdaran si Kabiyesi lọrun, ti wọn si ni o kere tan, ile-ẹjọ mẹfa ọtọọtọ to jẹ ile-ẹjọ giga, ati Majisreeti ni awọn eeyan ti wọ ọba naa lọ niluu Ilọrin ati Ọffa, to si n ta ẹrẹ si epo aala araalu Odo-Ọwa, ati gbogbo agbegbe rẹ lapapọ. Bo ti n da wahala silẹ laarin awọn ọdọ lo n da wahala silẹ laaarin awọn agbaagba ilu, ko gba ilẹ onilẹ, ko bọsọ lọrun awọn oloye, ko lu wọn ni gbangba, wọn lo tun lọwọ ninu iku Ọba Michael Adegoke Adimula to waja, wọn ni ki gomina rọ ọ loye kiakia, ko si koju igbẹjọ to tọ, nitori pe ilu ti kọ ọ lọba.

Leave a Reply