Imaamu ilẹ Ibadan tako aṣẹ awọn olori Islam, o kirun yidi l’Agodi

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Pẹlu bi igbimọ National Supreme Council for Islamic Affairs (NSCIA) ṣe kede pe aawẹ Ramadan gbọdọ tẹsiwaju l’Ọjọruu, ọjọ kejila, oṣu karun-un, ọdun 2021, nitori awọn ko ti i ri oṣu Shawal to kan lẹyin Lamulana yii, Imaamu Ilẹ Ibadan, Alaaji AbdulGaniu Abubakry Agbọtọmọkekere, ti ṣaaju irun yidi fawọn eeyan l’Agodi, wọn ni aawẹ tawọn ti pari lọdun yii na.

Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, naa wa lara awọn to kirun lẹyin Imaamu yii, bẹẹ ni Igbakeji gomima ipinlẹ Ọyọ, Alaaji Rauf Ọlaniyan, naa kirun Yidi laaarọ oni, lẹyin Imaamu Agbọtọmọkekere.

Ana ode yii ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun ni Imaamu ilẹ Ibadan ti kede loju opo Fesibuuku rẹ, pe oun yoo kirun lowurọ Ọjọruu, nitori mọkandinlọgbọn laaawẹ, o si ti pe.

Bo tilẹ jẹ pe Yidi Agodi naa ko kun to bo ṣe maa n kun tẹlẹ, nitori ọpọ eeyan ṣi n gbaawẹ Ramadan gẹgẹ bii aṣẹ awọn olori ẹsin Islam, sibẹ, awọn araalu kọọkan naa ti wọn lawọn ko gbaawẹ mọ, darapọ mọ wọn l’Agodi, wọn si kirun.

Ẹ oo ranti pe lọdun kẹta sẹyin, nigba ti wọn ni ọgbọn (30) ni aawẹ ọdun naa, Imaamu Agbọtọmọkekere ko duro gba ọgbọn, lẹyin ọjọ kọkandinlọgbọn lo ṣiwaju irun yidi fawọn to tẹle e.

Leave a Reply