Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọjọ Abamamẹta, Satide, yii ni tanka epo kan deede gbina niwaju ọfiisi Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun.
Bo tilẹ jẹ pe ina to sọ naa ko ṣọṣẹ kankan ju tanka epo to jo naa lọ, ko sohun to jẹ ki eyi ri bẹẹ ju pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana tete debẹ, wọn si ri ina ọhun pa.
Dẹrẹba to wa mọto epo bẹntiroolu naa, Nurudeen Yusuf, ṣalaye pe ninu ẹnjinni ọkọ naa ni kinni kan ti ṣana, nigba tawọn yoo si fi wo o ni ina nla ṣẹ yọ niwaju ọfiisi gomina ti mọto naa de lasiko yẹn.
O ṣalaye pe Ijọra, niluu Eko, loun atawọn ọmọ ẹyin ọkọ meji ti n gbe bẹntiroolu naa bọ, Adatan, l’Abẹokuta, lawọn si n lọ ko too di pe ina sọ lojiji, to jo mọto naa run.
Ohun to jọọyan loju ninu iṣẹlẹ yii ni pe tanka to n gbe epo bọ lati ọna jinjin bii eyi ko ni ohun ti wọn fi n pana ninu ọkọ bi ina ba ṣẹ yọ lojiji bii eyi.