INEC ṣatunṣe si ọjọ ti awọn eto idibo yoo waye lọdun to n bọ

 Ni bayii, ajọ eleto idibo ilẹ wa ti ṣatunṣe si ọjọ to yẹ ki eto idibo gomina ati aarẹ wayẹ nilẹ wa lọdun to n bọ. Wọn ti gbe e kuro ni ọjọ to yẹ ko waye tẹlẹ, wọn si ti kede ọjọ mi-in bayii.

Eto idibo aarẹ ti wọn ti kọkọ kede pe yoo waye ni ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ọdun 2023 tẹle, ni wọn ti sun si ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023. Nigba ti ibo si ipo gomina ati ileegbimọ aṣofin yoo waye ni ọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun to n bọ.

Tẹ o ba gbagbe, Alaga ajọ eleto idibo ilẹ wa, Yakubu Mahmood, ti kọkọ sọ lọsẹ to kọja pe ti Aarẹ Buhari ko ba tete fọwọ si atunṣe ofin eto idibo, o ṣee ṣe ko ṣakoba fun ọjọ ti idibo maa waye, ti awọn si le sun awọn ọjọ naa siwaju. Ṣugbọn pẹlu pe Buhari fọwọ si i lọsẹ to kọja naa, atunṣe pada ba awọn ọjọ idibo ọhun.

Leave a Reply