Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Kọmisanna fun ajọ eleto idibo nilẹ yii, ẹka ti ipinlẹ Kwara (REC), Malam Garba Attahiru Madami, ti ni ibanujẹ ọkan lo jẹ bi awọn ẹgbẹ oṣelu kan nipinlẹ Kwara ṣe n faaye gba awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ki wọn maa forukọ silẹ lẹẹmeji, o ni ẹwọn ọdun kan ni wọn fi n runmu.
Madami sọrọ yii lasiko to n ṣe ipade pẹlu awọn adari wọn niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ Kwara. O sọ pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ to forukọ silẹ lẹẹmeji ẹwọn ọdun kan ati owo itanran miliọnu kan Naira ni ijiya to wa fun un, ati pe wọn yoo pa orukọ rẹ rẹ patapata ti ko ni i lẹtọọ lati dibo.
O fi kun un pe ile-ẹjọ yoo tun wa ti yoo maa dajọ awọn to ba taṣẹ agẹrẹ si ofin eto idibo, fun idi eyi, ki onikaluku lọọ sowọ agbejẹ mọwọ.
Madami ni pẹlu awọn ohun eelo imọ ẹrọ igbalode ti ajọ naa fẹẹ lo, ko ni i si aaye fun magomago lasiko eto idibo to n bọ.
O ṣeleri pe ajọ eleto idibo nipinlẹ Kwara yoo ṣeto idibo ti ko ni i ni wayo kankan ninu, ti yoo si lọ ni irọwọ rọṣẹ.