Faith Adebọla
Ajọ eleto idibo apapọ ilẹ wa, Indepedent National Electoral Commission, INEC, ti kede pe eto idibo sipo gomina ati ileegbimọ aṣofin ipinlẹ tawọn ọmọ Naijiria n reti lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2023, iyẹn ọjọ mẹta sasiko yii, ko ni i waye mọ, wọn ti sun un siwaju fun ọsẹ kan.
Alaroye gbọ pe INEC dori ipinnu lati sun eto naa siwaju nibi ipade akanṣe kan ti awọn lọgaa-lọgaa ajọ naa atawọn kọmiṣanna INEC kaakiri awọn ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa nilẹ wa, pẹlu ti Abuja, tilẹkun mọri ṣe laṣaalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta yii, lolu-ileeṣẹ ajọ ọhun to wa l’Abuja. Nnkan bii aago meje alẹ nipade naa bẹrẹ, alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, lo si ṣalaga rẹ.
Ọkan ninu awọn Kọmiṣanna INEC ti ko fẹ ki wọn darukọ oun, sọ funweeroyin Punch pe ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta yii, ni eto idibo naa yoo waye bayii, dipo ọjọ kọkanla ti wọn ṣeto rẹ si tẹlẹ.
O ni INEC yoo ṣi sọ awọn ohun to ṣokunfa ayipada ojiji yii di mimọ faraalu ti wọn ba ti pari ipade naa.
Ẹ oo ranti pe gẹrẹ ti eto idibo sipo aarẹ ti waye, ti wọn si ti kede esi idibo naa ni oniruuru awuyewuye ti n waye, bi wọn si ṣe n bẹnu atẹ lu INEC fun bi eto idibo naa ṣe lọ, bẹẹ lawọn mi-in n gboṣuba fun wọn.
Bakan naa lawọn rukerudo ti bẹrẹ si i ṣẹlẹ lawọn ipinlẹ kan atawọn agbegbe kan, leyii to mu ki eto idibo to n bọ lọna ọhun kọ ni lominu.
A o maa mu ẹkunrẹrẹ alaye ti INEC ba ṣe lori ayipada yii wa fun yin bo ba ṣe n lọ, ẹ tẹti leko.