Reluwee fori sọ bọọsi BRT l’Ekoo, eeyan meji ku, ọpọ fara pa yannayanna

Faith Adebọla

O kere tan, eeyan meji ti pade iku ojiji, nigba ti ọpọ fara pa yannayanna, ti pupọ ninu wọn si wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun latari ijamba ọkọ kan to waye laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹta yii, reluwee lo ka ọkọ akero gbọgbọrọ ti ijọba Eko, eyi ti wọn n pe ni BRT (Bus Rapid Transit) mọ oju-irin rẹ, ni wọn ba fori sọ ara wọn.

Alaroye gbọ pe awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn n lọ sọfiisi wọn gbogbo lagbegbe Ikẹja ni wọn kun inu ọkọ BRT ọhun.

Agbegbe PwD si Ṣogunlẹ, n’Ikẹja, niṣẹlẹ naa ti waye. Ẹnikan tọrọ naa ṣoju ẹ sọ pe bọọsi BRT lo fẹẹ ya wọle lati ori titi marosẹ Sango si Oṣodi, o fẹẹ gba iyana to wa ni PwD wọle sagbegbe Ikẹja, o si ni lati kọja loju irin reluwee kan to wa nibẹ tawọn ọkọ maa n gba, amọ ko mọ pe reluwee n bọ, ati pe o ti sun mọ itosi, nigba to de oju irin naa, awọn ọkọ to wa niwaju BRT ko jẹ ki irin rẹ le ya kankan, bẹẹ lọgọọrọ ọkọ ti wa lẹyin, ko ṣee ṣe lati rifaasi, n ni reluwee to n bọ lati Agege si Apapa, tawọn ero to n lọ sibiiṣẹ ounjẹ oojọ wọn kun inu rẹ tẹmutẹmu ba ka a mọ.

Ninu fidio kan to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara nipa iṣẹlẹ ọhun, a ri i bi reluwe naa ṣe wọ ọkọ BRT yii siwaju, sẹgbẹẹ gọta kan, ibẹ lawọn mejeeji fi tipatipa duro si, bẹẹ lẹjẹ eeyan n ṣan lara bọọsi naa, gbogbo gilaasi windo, ati tiwaju ati tẹyin, lo ti fọ, ọpọ ni afọku gilaasi naa ṣe leṣe.

Lasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ, awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri l’Ekoo, Lagos State Emergency Management Agencies (LASEMA) ti de ibi iṣẹlẹ naa, wọn si ti n ṣeranwọ lati doola ẹmi awọn to ha sinu awoku BRT. Oju awọn windo ti gilaasi rẹ ti fọ ọhun lọpọ eeyan n tiraka lati gba jade, awọn gende to wa nitosi si n ṣeranwọ fun wọn. A gbọ pe oku eeyan meji ni wọn ṣi ri gbe jade, nigba ti wọn n fi ọkọ agbokuu-gbalaye, iyẹn ambulansi, ko awọn to fara gbọgbẹ lọ sawọn ileewosan to wa nitosi, ki wọn le tete ri itọju pajawiri gba.

Bakan naa lawọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ l’Ekoo, LASTMA, ti n ṣiṣẹ aṣelaagun nibẹ, awọn ọlọpaa si wa nibẹ pẹlu lati pese aabo, wọn n le awọn ero rẹpẹtẹ ti wọn n woran, ti wọn si n daro nibi iṣẹlẹ naa sẹyin, tori awọn janduku atawọn gbewiri ti wọn le wa laarin ero, tabi ti wọn le fẹẹ jale.

Leave a Reply