Awọn ṣọja mu gende mẹta pẹlu kaadi idibo ẹgbẹrun kan aabọ ninu ile akọku

Faith Adebọla, Eko

Pẹlu bi eto idibo sipo gomina ṣe ku ọsẹ kan bayii, ọwọ palaba awọn afurasi arufin mẹta kan ti segi nipinlẹ Eko, awọn ṣọja, pẹlu iranlọwọ awọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ ijọba apapọ, iyẹn awọn DSS, ni wọn mu wọn ninu ile akọku kan ti wọn fori pamọ si, kaadi idibo alalopẹ  ẹgbẹrun kan, ọgọrun-un mẹfa, ati mọkanlelaaadọrin (1,671), awọn iwe idibo rẹpẹtẹ, ni wọn ka mọ wọn lọwọ, pẹlu awọn nnkan ija oloro ati oogun abẹnugọngọ.

Agbegbe Olodi-Apapa, niṣẹlẹ naa ti waye, nijọba ibilẹ Ajeromi-Ifẹlodun, nipinlẹ Eko.

Lasiko ti wọn n ṣafihan awọn afurasi naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Keji yii, ni ẹka ileeṣẹ ologun to wa n’Ikẹja, Ọgagun Isang Akpaumontia, to jẹ kọmanda awọn ologun ẹka naa ṣalaye pe olobo kan lo ta awọn pe awọn kan ni kaadi idibo rẹpẹtẹ lọwọ, leyii tofin sọ pe ẹnikan ko gbọdọ ni ju ẹyọ kan lọ, n ni wọn ba ranṣẹ sawọn DSS lati fimu finlẹ, ti ọwọ si to wọn.

Ọpọ awọn kaadi idibo naa lo jẹ awọn ti wọn tẹ jade lọdun 2021, yatọ sawọn ti wọn ṣe ni ọdun 2011 ati 2012. Ọpọ awọn to ni kaadi naa lo jẹ olugbe Eko, tori adirẹsi Eko lo wa lara wọn.

Ọgagun naa sọ pe: “Laaarọ yii, ọwọ tẹ awọn ọdọkunrin mẹta kan pẹlu kaadi idibo rẹpẹtẹ nikaawọ wọn. Olobo kan lo ta wa nipa wọn, ta a fi ri wọn mu pẹlu ajọṣepọ awọn ẹṣọ DSS.

“Apapa la ti mu wọn, yatọ si kaadi idibo, a tun ba egboogi oloro lọwọ wọn, oogun abẹnugọngọ, aake ati ọbẹ aṣooro, pẹlu awọn nnkan ija mi-in.

“Wọn sọ fun wa pe ẹni to ni ile ta a ka wọn mọ naa lo ran awọn niṣẹ, wọn lotẹẹli kan lo wa ni tiẹ, a wa a lọ sotẹẹli ti wọn sọ ọhun, ṣugbọn a ko ri i, o ti sa lọ ka too debẹ.

“A maa fawọn tọwọ ba yii ṣọwọ si olu-ileeṣẹ awọn ologun, ki wọn le gbe igbesẹ to yẹ lori wọn gẹgẹ bofin ṣe la a kalẹ, ati kawọn ọdọ mi-in le fi tiwọn ṣe arikọgbọn,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply