Monisọla Saka
Ọwọ ileeṣẹ to n gbogun ti oogun oloro nilẹ yii, NDLEA, ti tẹ awọn agbero inu papakọ ofurufu Murtala Muhammad, Ikẹja, niluu Eko, meji kan lasiko ti wọn fẹẹ gbe igbo sọda soke okun.
Agbẹnusọ ajọ naa, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022 yii.
Babafẹmi ṣalaye pe inu lailọọnu ti wọn maa n ko ounjẹ awọn ọmọde ti wọn n pe ni Golden Morn si ni wọn tọju ẹru ofin naa si, ti wọn si ko o gba ileeṣẹ Skyway Aviation Handling Company, ibudo awọn SAHCO, ninu papakọ ofurufu naa lọ si Dubai.
O ni niṣe ni wọn kẹ ẹru naa kalẹ si ibudo ajọ SAHCO, ki ọkan ninu awọn oṣiṣẹ papakọ ofurufu naa too ko firi ẹ, to si taari ẹ sọdọ awọn ajọ NDLEA.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, iwadii ti wọn ṣe lọwọ fi tẹ ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Ọlatunbọsun Abimbọla, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34) to lọwọ ninu bi ẹru naa ṣe debẹ.
Babafẹmi ni, “Lọjọ Ẹti, Furaidee, lọwọ ba afurasi ọhun to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ eto irinna Ashadox Logistics Services, ti wọn maa n ba awọn eeyan gbe ẹru ranṣẹ.
Nigba to maa jẹwọ, o ni ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ tori ki i ṣe oun loun ran ara oun, aṣẹ ti ọga oun, Oloyede Abiọla, toun n ṣiṣẹ labẹ ẹ pa loun tẹle. Ọrọ ẹnu Abimbọla yii lo mu ki wọn tọpasẹ ọga ẹ yẹn lọ, lọgan ni wọn si ti lọọ gbe e.
Ọkunrin ẹni ogoji ọdun to wa lati Iwọ Oorun Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, yii ni loootọ loun pa Abimbọla laṣẹ lati gbe ẹru naa sibẹ, ṣugbọn nitori eto aabo to gbopọn tawọn ajọ NDLEA gun le lọwọ bayii loun o ṣe mọ ohun toun le ṣe si i ju ki awọn fi ẹru naa sibẹ dipo ki wọn ka a mọ awọn lọwọ”.
Babafẹmi tun ṣalaye siwaju pe kawọn eeyan maa kiye sara nigba gbogbo, tori o ṣee ṣe ki wọn gbe iru ẹru yii fun eeyan lati gbe e jiṣẹ, ti ko ni i mọ, koda mọlẹbi eeyan le gbe e leeyan lọwọ toluwarẹ ko ni i mọ pe wahala lo gbe foun.
Ọga agba ajọ NDLEA, Baba Marwa, gboṣuba fun ikọ to n gbogun ti oogun oloro ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed, Ikẹja, fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe.
O waa ke pe awọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA to ku kaakiri ilẹ Naijiria lati ma ṣe figba kankan tura silẹ ninu ija wọn lati gba orilẹ-ede yii silẹ lọwọ awọn to n gbe oogun oloro atawọn to n lo o.