Ipinlẹ Ọṣun ni Sẹfiu atawọn ọrẹ rẹ ti digun ja pasitọ lole, ipinlẹ Ogun lọwọ ti tẹ wọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Wale Ọlọkọde, ti ṣafihan ikọ adigunjale ẹlẹni-mẹta kan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. Awọn afurasi naa ni Sẹfiu Adeboye, ẹni ọdun mejilelogun, Adekunle Ọdẹkanyi, to jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun ati Adewale Simon to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogoji.

Alufaa ijọ Anglican kan niluu Akiribọtọ, nijọba ibilẹ Ayedaade, nipinlẹ Ọṣun, ni wọn lọọ ka mọle lọjọ kejidinlogun, oṣu keje, ọdun yii.

Pẹlu ibọn, aake ati ada ni wọn wọnu ile naa ni nnkan bii aago kan oru ọjọ ọhun. Wọn gba foonu mẹfa ati kọmputa alagbeeka kan, lẹyin naa ni wọn gba kọkọrọ mọto Toyota Corolla alawọ pupa ti alufaa naa n lo, ti wọn si gbe e lọ.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn afurasi naa, Adekunle, ṣe sọ fun ALAROYE, ibi kan ti wọn n pe ni Shrine, nipinlẹ Eko, ni wọn kọkọ gbe mọto naa lọ.

Lẹyin ti wọn jaye tan nibẹ ni wọn mori le agbegbe kan nipinlẹ Ogun, ṣugbọn mọto naa daṣẹ silẹ, asiko ti wọn si n tun un ṣe lọwọ ni ọwọ awọn ọlọpaa tẹ wọn.

Ọlọkọde ṣalaye pe bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ ni alufaa yii ti lọọ fi to awọn ọlọpaa agbegbe Gbọngan leti, lọgan lawọn yẹn naa si ti bẹrẹ iwadii titi ti ọwọ fi tẹ Sẹfiu ati Adekunle.

Nigba ti wọn ko wọn wa siluu Akiribọtọ ni wọn tu aṣiri Simon yii, awọn ọlọpaa si mu oun naa, ṣugbọn ọwọ ko ti i tẹ ẹni kẹrin ti wọn jọ ṣiṣẹ naa.

Ọlọkọde fi kun ọrọ rẹ pe laipẹ lawọn afurasi naa yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply