Amofin agba Babatunde Faṣhọla, ti da sọrọ to n ja ran-in-ran-in nilẹ lori apa ibi ti aarẹ yoo ti jade lọdun 2023.
Faṣhọla ti ke sawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ki wọn bọwọ fun ọrọ adehun to ti wa nilẹ lori bi wọn yoo ṣe maa pin ipo Aarẹ laarin agbegbe awọn ẹya to wa ni Naijiria.
O ni ṣaaju eto idibo ọdun 2015, lawọn agbaagba oloṣelu ti wọn kora wọn jọ lati da ẹgbẹ oṣelu APC silẹ ti ni ajọsọ ̀ọrọ, bo tilẹ jẹ pe ko si ninu akọsilẹ nipa ibi ti Aarẹ yoo ti jade lọdun 2023 lẹyin ti Buhari ba pari eto iṣakoso ẹ.
O ni adehun ṣe pataki pupọ, ti eeyan ba si le tẹle e, yoo mu ilọsiwaju ba orilẹ-ede. Ọkunrin oloṣelu yii wa ninu awọn to jokoo nigba naa lọhun-un lati da ẹgbẹ APC silẹ, ni kete ti Buhari si ti jawe olubori, toun naa ko si nipo gomina mọ, ni wọn ti ba a wa nnkan, nibi to ti jẹ minisita akọkọ to maa ni ipo mẹta ninu ijọba Buhari.
Faṣhọla ti waa ke si gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lati wa ni iṣọkan, bẹẹ lo tun fidi ẹ mulẹ pe ko si ọna ti ẹgbẹ oṣelu PDP le gba ti wọn le ba APC laelae nidii oṣelu, nitori pupọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun paapaa ni wọn tun n darapọ mọ APC bayiì, eyi to fi han pe niṣe ni ẹgbẹ oṣelu naa n tẹsiwaju si i.
Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni gomina ipinlẹ Ebonyi, David Umahi, kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, to si waa darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Ohun ti gomina naa sọ pe o mu oun kuro ninu ẹgbẹ PDP ko ju bi ẹgbẹ naa ko ṣe ronu ri lati lo ọmọ Ibo gẹgẹ bii oludije fun ipo Aarẹ latigba ti eto ijọba awa-ara-wa ti bẹrẹ pada lọdun 1999.
Yatọ si eyi, alaga fidi-hẹe ẹgbẹ naa, Mai Mala Buni, ẹni ti ṣe gomina ipinlẹ Yobe, naa tun gbe igbesẹ kan laipẹ yii, nigba to ko awọn kan sodi lọọ ki Aarẹ tẹlẹ, Goodluck Ebere Joanthan, nile lasiko tiyẹn ṣe ọjọọbi ẹ. Ohun tawọn eeyan to mọ tifun-tẹdọ oṣelu n sọ ni pe gbogbo ọgbọn ni APC n wa bayii lati fa oju ọkunrin naa mọra lati waa darapọ mọ wọn.
Bẹẹ ni wọn n sọ pe o ṣee ṣe ki wọn fa ọkunrin naa kalẹ fun ipo Aarẹ, paapaa bo ṣe jẹ pe saa kan pere lo tun le ṣe nile ijọba, ati pe lẹyin saa kan ẹ yii lọmọ Hausa yoo gba a pada lọwọ ẹ.