Ipo ti mo ba mọlẹbi ọmọbinrin ti wọn pa s’Ọjọta lasiko iwọde ‘Yoruba Nation’ ṣe mi laaanu lo jẹ ki n fun wọn lowo-Mr Macaroni

Faith Adebọla

Gbajugbaja adẹrin-in poṣonu ilẹ wa nni, Ọgbẹni Debọ Adedayọ, tawọn eeyan mọ si Mista Makaroni ti fi ẹbun idaji miliọnu naira (#500,000) ṣetọrẹ aanu fawọn mọlẹbi Jumọkẹ Oyeleke, ọmọbinrin kan ti wọn laṣita ibọn awọn ọlọpaa lo dẹmi-in ẹ legbodo lasiko iwọde ‘Yoruba Nation’ lọjọsi, o ni aanu awọn mọlẹbi naa lo ṣe oun.

Jumọkẹ, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, ni wọn yinbọn pa lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹta, oṣu yii, niwaju ṣọọbu ọga rẹ nibi to ti n ba wọn ta miniraasi atawọn nnkan mimu ẹlẹrindodo, o n patẹ ọja lọwọ niwaju ṣọọbu naa nibọn ba a, to si ku loju-ẹsẹ.

Nigba ti akọroyin ALAROYE pe e lori foonu lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, Mista Macaroni to ṣabẹwo sile awọn mọlẹbi oloogbe naa lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, sọ pe “Aanu awọn mọlẹbi ọmọbinrin naa ṣe mi gidi, niṣe ni wọn n sunkun. Wọn ni ọmọbinrin ti wọn pa yii lo n gbe bukaata famili wọn, owo to n ri nibi iṣẹ ti wọn pa a si yii naa lo si fi n tọju iya rẹ atawọn aburo rẹ mẹta.

Yara kan ninu ile pako kan bayii ni wọn n gbe, ni ọna kan to lọ si ṣọọṣi Ayọrinde, l’Ọjọta. Ile naa ko woju u ri rara, ko si sẹni to ya si wọn latigba tiṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ, wọn lawọn ọlọpaa o gba pe ọwọ awọn eeyan wọn niṣẹlẹ aburu naa ti wa, ko si si oluranlọwọ kan fun wọn.

Wọn sọ fun mi pe ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin naira (#700,000) ni wọn ṣaaji wọn pe ki wọn san fun ayẹwo ti wọn ṣe lati mọ iru iku to pa ọmọbinrin naa, eyi tawọn eleebo n pe ni autopsy, ati owo itọju oku ni mọṣuari.

Nigba ti mo gbọ iroyin iṣẹlẹ yii, aanu wọn ṣe mi gidi, mo ro o pe nnkan to ṣẹlẹ yii le ṣẹlẹ si mi, o si le ṣẹlẹ sẹnikẹni, idi niyi ti mo fi ṣeranwọ ti mo ṣe. Ki i ṣe pe owo pọ lọwọ mi to bẹẹ, ninu owo ti mo n tujọ pamọ naa ni mo fa yọ, ki wọn le mọ pe ẹni to bikita nipa wọn ṣi wa.”

Ọpọ awọn ololufẹ oṣere yii atawọn araalu ni wọn ti kan saara si i fun igbesẹ to gbe ati itọrẹ aanu to ṣe yii, wọn si ṣadura fun un lori ikanni ayelujara rẹ, wọn lawọn mọyi bo ṣe jẹ ẹlẹyinju-aanu ẹda.

Leave a Reply