Irẹsi ni James fẹẹ lọọ ra to fi sọnu fọdun marundinlaaadọta, oṣu keje yii lo wọle de wẹrẹ

Ko kuku sohun ti ko ṣee ṣe f’Ọlọrun b’asiko ba to lati ṣe e, iyẹn gan-an ni ti baba agbalagba to jokoo ṣikeji lapa osi yii, ẹni ti orukọ rẹ n jẹ James Mwaura, ọmọ orilẹ-ede Kenya to sọnu lọdun mẹrindinlaaadọta (47) sẹyin, to si pada wa saarin awọn famili ẹ wẹrẹ lọjọ kejilelogun, oṣu keje yii, ti i ṣe Ọjọbọ to kọja.

Ọdun 1974 ni James Mwaura jade nile awọn obi rẹ to wa ni Molo, Nakuru, ni Kenya, irẹsi ti wọn yoo jẹ ni wọn ran an pe ko lọọ ra wa ni ṣọọbu kan, ẹni ọdun mẹtalelogun lo wa nigba naa, o si jade lati jiṣẹ ọhun. Ṣugbọn fun idi kan tabi omi-in tawa ko mọ, gendekunrin naa ko mọna ile mọ, o si bẹrẹ si i rin kiri.
Olu ilu Kenya ti i ṣe Nairobi lo ti pada ba ara rẹ, inu rẹ si kọkọ dun nigba to ranti pe oun ni ẹgbọn kan nibẹ. Aṣe ẹgbọn paapaa ti kuro niluu ọhun, ni ọkunrin yii ko ba rẹni kankan foju jọ.

Eyi lo mu un gba ilu kan ti wọn n pe ni Naro Moru lọ, ni Kenya nibẹ, n lo ba n ṣiṣe aje nibẹ, o gba kamu nigba ti ko gburoo ẹnikan kan ninu awọn eeyan rẹ to fi silẹ mọ. James fẹyawo sibẹ, o si bẹrẹ si i bimọ.

Afi laipẹ yii toun naa di ẹni to n lo foonu, to n ri ohun to n lọ lori ayelujara, nigba naa ni baba to ti pe aadọrin ọdun bayii (70) naa ri ẹnikan ti oju rẹ jọ ẹni to mọ lori Fesibuuku, o si fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si i nibẹ pe oju rẹ jọ ẹni ti oun mọ o. O juwe ara rẹ fun ẹni naa, o si pada mọ pe ọmọ ẹgbọn oun ọkunrin ni.

 

Awọn mejeeji gba lati foju kan ara wọn ko too di ohun ti awọn famili yooku yoo mọ, bẹẹ naa ni wọn si ṣe e. Nigba ti ko ruju mọ pe James to lọọ ra irẹsi ti ko wale mọ ree, gbogbo ẹbi rẹ lo tẹwọ gba a l’Ọjọbọ to kọja yii to wọle de ninu aṣọ oyinbo (suutu) alawọ buluu kan.

Baba sọ fawọn to fi silẹ lọmọde, tawọn naa ti dagba bayii, pe oun naa ti di baba-baba, nitori oun atiyawo oun ti bimọ mẹta, awọn si ti ni ọmọ-ọmọ mẹrin. N ni gbogbo famili ba fidunnu ki wọn kaabọ, wọn dupẹ lọwọ Ọlọrun to mu wọn ri eeyan wọn pada, nipasẹ ẹrọ ayelujara.

 

Leave a Reply