Irọ ni, Tinubu ko tọ sara nigba to lọọ ki Awujalẹ, awọn ọta lo n sọ bẹẹ kiri-Ajiboye

Adewumi Adegoke

Ọga agba eto iroyin ati ipolongo fun (SGMC) ẹgbẹ to n ṣatilẹyin fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lati di aarẹ Naijiria lọdun 2023, Ọtunba Biọdun Ajiboye, ti sọ pe ko si ootọ ninu fidio kan to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara, nibi to ti ṣafihan ẹyin aṣọ Bọla Ahmed Tinubu to rin gbindin fomi, ti wọn si n sọ pe niṣe ni baba naa tọ sara nitori aisan kan ti ki i jẹ ki eeyan le da itọ duro to ba n bọ to n ṣe e.

Ninu fidio ọhun ni aṣọ Aṣiwaju ti tutu lẹyin lasiko to dide lati dọbalẹ fun Awujalẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Adetọna, nigba to lọọ ki i laafin rẹ lati fi erongba rẹ lati dupo aarẹ Naijiria lọdun to n bọ han.

Eyi ni awọn eeyan ri ti wọn fi n pariwo pe Tinubu tọ sara, ti wọn n sọ pe ara baba naa ko ya, ati pe niṣe lo yẹ ko lọọ jokoo, ko tọju ara rẹ, ko yee daamu ara rẹ pe oun fẹẹ di aarẹ Niajiria pẹlu aiyaara.

Ninu atẹjade ti ọkunrin naa gbe jade sori ẹrọ ayelujara, eyi to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti sọ pe ‘‘Awọn oniṣẹ irọ kan ti tun bẹrẹ iroyin eke wọn. Lopin ọsẹ to kọja, Aṣiwaju Bọla Tinubu ṣabẹwo sawọn ọba pataki mẹrin nipinlẹ Ogun. Gbogbo awọn oriade atawọn ijoye lawọn agbegbe naa ni wọn si gba a tọwọ-tẹsẹ, to fi mọ awọn omilẹgbẹ ero ti wọn tẹle e.

‘‘Aṣeyọri ti Tinubu ṣe lasiko abẹwo sawọn ọba nla nla yii ti mu ki awọn ọta itẹsiwaju, awọn ti wọn kun fun ikoriira, ti wọn n gbin igi ainiṣọkan ni wọn gbe irọ nla kan jade lati ba ode daadaa yii jẹ. Ni asiko yii, ohun ti wọn n sọ ni pe Tinubu tọ sara.

‘‘Ka tiẹ waa ni ohun ti wọn n sọ ti awa ko gba pe ootọ ni yii ba ṣẹlẹ, ṣe ibi isalẹ ẹsẹ rẹ ni yoo waa tutu, abi ibi idi rẹ. To ba jẹ pe loootọ lo tọ sara, ti aṣọ rẹ sin rin gbindin fun itọ, ṣe ko ni i fẹẹ daṣọ bo o, ṣe pẹlu rẹ naa ni yoo tun gbiyanju lati dọbalẹ fun Awujalẹ ilẹ Ijẹbu niṣoju gbogbo eeyan to wa nibẹ.

Wọn ṣe arọnda aworan yii ni, ati pe ọpọlọ wọn ti ko tẹwọn daadaa lo ti wọn debi ti wọn ti n gbe iroyin ti ki i ṣe ootọ yii jade.

‘‘Pẹlu ẹ naa, fidio wọn fi han pe lẹyin to tọ sara lo tun ṣẹṣẹ waa dọbalẹ fun Awujalẹ. Awọn ti wọn wa nidii eremọde to biiyan ninu yii gbọdọ fi ọpọlọ kun ohun ti wọn n ṣe.

‘‘Eyi jẹ ọna mi-in lati ṣi wa niye kuro ninu ohun ti a n ṣe, ṣugbọn ko siye iṣini-niye tẹ ẹ le ṣe, bẹẹ ni ko si bi ẹ ṣe le ba Aṣiwaju jẹ to maa din okiki to ni nidii oṣelu ku.’’  Bẹẹ ni Ọtunba Biọdun Ajiboye pari ọrọ rẹ, to si gbe aworan si i.

Ṣugbọn ọpọ ni ko gba ọrọ yii gbọ o, paapaa ju lọ awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn, ti wọn wa ni aafin Awujalẹ nigba ti Aṣiwaju dide. Wọn ni loootọ ni, ki i ṣe irọ pe aṣọ Aṣiwaju tutu nigba to dide lati ki Awujalẹ, ko si le ṣee ṣe fun un lati ni oun maa jokoo ba kabiyesi sọrọ nitori ko sẹni to maa n ki ọba lori iduro, eyi ni ko fi si ọna to le gbe e gba lai jẹ pe o dide ki ọba alaye naa.

Awọn mi-in sọ pe agba oloṣelu yii paapaa le ma mọ pe oun ti tọ sara nitori awọn ti arun yii maa n ṣe ki i mọ nigba mi-in ti wọn fi maa tọ.

Yatọ si eleyii, awọn kan tun n sọ lori ẹrọ ayelujara pe bi ọrọ naa ko ba jẹ ootọ, awọn to gbe e ko ni i gbe e sita nitori wọn mọ pe bi awọn ba fi le gbe fidio to tabuku eeyan bẹẹ, ti ki i si i ṣe otitọ jade, ẹwọn ni iru ẹni bẹẹ fi n ṣere nitori loju-ẹsẹ ni ẹni ti wọn fẹẹ ba lorukọ jẹ yii yoo gbe wọn lọ si kootu.

Ọpọ awọn ti wọn ti sọrọ lori fidio yii ni wọn n sọ pe ootọ ni, irọ ti ko si ṣee bo ni awọn ti wọn n sọ pe ko ri bẹẹ n pa.

Ṣugbọn awọn ọmọlẹyin Aṣiwaju ti sọ pe baba naa ko tọ sile, wọn ni wọn ṣe arọnda fidio ti wọn gbe jade ni.

Leave a Reply