Iru ki waa leleyii! Sherifat n mura idanwo Wayẹẹki lọwọ lo fi binu para ẹ n’Ikorodu

 Faith Adebọla

Orin wo la fẹẹ kọ si gbẹdu lọrọ da pẹlu bi ibanujẹ ati ọgbẹ ọkan ṣe bo awọn mọlẹbi atawọn aladuugbo ọmọbinrin kan ti wọn porukọ ẹ ni Sherifat Suleiman, to jẹ pe o ku ọjọ meloo kan ko bẹrẹ idanwo Wayẹẹki (WAEC) oniwee mẹwaa rẹ lo binu gbe majele jẹ, to si para ẹ danu.

Ọmọ ọdun mọkanlelogun to rẹwa lobinrin lọmọ ọhun, ọdọ ẹgbọn rẹ ọkunrin, Mọliku Sulaimọn, loun atawọn aburo ẹ meji kan n gbe ni Opopona Ọlọrunṣogo Iyewa, adugbo Iṣawo, lagbegbe Ikorodu, nipinlẹ Eko, ṣugbọn baba lo da oun ati Mọliku pọ, wọn ki i ṣe ọmọ iya kan naa.

ALAROYE gbọ pe ilokulo bii omi ojo lẹgbọn rẹ ẹni ogoji ọdun yii n lo awọn aburo rẹ, ọpọ igba ni wọn lo si maa n fibinu na Ṣherifat bii ewurẹ, latari pe oun lo dagba ju laarin wọn.

Laaarọ ọjọ tiṣẹlẹ yii ṣẹlẹ, wọn ni iyawo Mọliku lo ran oloogbe yii niṣẹ pe ko lọọ ba oun gba burẹdi to n ta wa ni bekiri ti wọn ti n gba burẹdi, igba tọmọ naa si de, o gbe burẹdi naa soke kanta kan ninu ile naa.

Ṣugbọn nigba tiyawo Moliku yoo fi yẹ burẹdi wo lọwọ iyalẹta, awọn larinka ajẹ-loju-onile ti ṣere dedii burẹdi, wọn si ti jẹ lara ẹ. Niyawo naa ba binu sọrọ eebu si Ṣherifat, o si fẹjọ rẹ sun ọkọ rẹ, o ni Ṣherifat ni ko tọju burẹdi ọhun daadaa tawọn eku fi raaye debẹ.

Tori ọrọ yii ni Mọliku ṣe ki paṣan mọlẹ, ti wọn lo fin ọmọbinrin yii tinu tẹyin, o larungun ọmọ ati ọta aje ni.

Boya ijiya ọhun lo dun ọmọbinrin yii to fi fi ookan kun eeji, to ro o pe o san koun kuku ku ju koun maa jiya bii eyi, Ọlọrun lo ye. Bọmọ ọhun si ṣe rowo ra majele Sniper, ẹnikan o le sọ, ṣugbọn ohun ta a ri gbọ ni pe niṣe ni Sherifat tilẹkun yara toun atawọn aburo ẹ n sun si mọri, to si da majele ọhun jẹ, lo ba gbẹmin ara ẹ laaarọ ọjọ Aje ọsẹ to kọja yii.

Loootọ la gbọ pe Mọliku sare gbe oloogbe ọhun digbadigba lọ sọsibitu nigba to n pọkaka iku, tawọn dọkita si fẹri ẹ mulẹ pe ẹni ti wọn gbe wa ti dakẹ loju ọna, ṣugbọn ohun to ya awọn tọrọ yii ṣoju wọn lẹnu, to si n mu ki wọn fura si ẹgbọn rẹ yii ni bo ṣe sare palẹ oku ọhun mọ funra rẹ, to si lọọ si in si ilu wọn ni Ijẹbu-Ode lai faaye silẹ pe ki wọn ṣayẹwo rẹ.

Awọn kan n sọ pe nitori oriṣiiriṣii apa ẹgba ati ami bi ọkunrin naa ṣe n ṣe Sherifat atawọn aburo rẹ niṣekuṣe to wa lara ọmọ naa lo fa a ti Moliku ṣe sare palẹ oku ẹ mọ, to si ṣẹnu mẹrẹn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Ọgbẹni Bala Elkana ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni ẹgbọn oloogbe naa ti wa lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n ṣewadii to lọọrin lati mọ hulẹhulẹ ohun to da ẹmi Sherifat legbodo bẹẹ.

 

Leave a Reply