Iwadii bẹrẹ lori iku to pa tọkọ-taya pẹlu ọmọ wọn mọle tuntun l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii, ko ti i sẹni kan pato to le sọ idi iku ojiji to pa ọdọmọkunrin kan, Ismail Adelẹyẹ, iyawo ẹ, Temitọpẹ Adelẹyẹ, ati ọmọ wọn ti ko ju ọmọ ọdun kan lọ, Kẹhinde Adelẹyẹ, laduugbo Suurudara, Bode-Olude l’Abẹokuta.

Eyi naa lo si fa a tawọn ọlọpaa fi bẹrẹ iwadii, ti awọn eeyan si n reti abajade ayẹwo oku wọn lọsibitu ijọba ti wọn gbe wọn lọ.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu keje yii, ni iku doro, to pa mọlẹbi tọjọ ori wọn ko to nnkan kan naa run. Koda, oorun akọkọ ti wọn sun ninu ile ti wọn ku si naa ree, wọn ṣẹṣẹ ko dele ọhun ni, awọn naa si lẹni akọkọ to gba ile naa, owo ti wọn san ni wọn fi sare ba wọn kọ ọ tan.

Ohun ti AKEDE AGBAYE gbọ ni pe omi maa n da awọn tọkọ-taya yii laamu nibi ti wọn n gbe tẹlẹ ni Bode-Olude kan naa. Wọn ni bi ojo ba ti rọ bayii, alaafia kan ko si fun wọn ninu ile ọhun mọ, nitori omi yoo wọle rẹkẹrẹkẹ ni. Eyi lo jẹ ki wọn kuro nibẹ lẹyin ti wọn sare ba wọn kọ ile ti wọn ti ku yii tan.

Ọjọ Satide to kọja ti i ṣe ọjọ kẹwaa, oṣu keje, ni wọn ko ẹru lọ sinu ile naa gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ko sun ibẹ lọjọ naa, afi lọjọ Sannde, lẹyin ti wọn kuro lode ariya igbeyawo kan. Ismail pẹlu iyawo atọmọ ẹ dari sile tuntun lalẹ ọjọ Sannde naa, eyi ti i ṣe ọjọ akọkọ ti wọn yoo sun nibẹ, ṣugbọn nigba ti ilẹ Mọnde yoo fi mọ, rẹrẹ ti run, eleeru ti sungi.

Iṣẹ awọn to n ta okuta ni Quarry ni Ismail tawọn eeyan mọ si T.Smart, n ṣe, Temitọpẹ iyawo ẹ lo jẹ aṣerunlọṣọọ (Hairdresser). Ọdun mẹrin sẹyin ni wọn di tọkọ-tiyawo, wọn kọkọ bimọ kan, ṣugbọn ọmọ naa ko si.

Oṣu kẹfa, ọdun 2020, ni Tọpẹ bi ibeji fun T.Smart, ọkan ku ninu awọn ọmọ naa, iyẹn Taye ku, o ṣẹku Kẹhinde nikan. Kẹhinde ọhun ṣẹṣẹ pe ọdun kan loṣu to kọja yii ni, wọn si ṣe ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kan naa fun ejirẹ yii daadaa. Afi bi iku ṣe da ẹmi oun atawọn obi ẹ legbodo lojiji ninu ile tuntun ti wọn ko lọ.

Ko tiẹ sẹni to tete mọ pe idile kan ti parun lojiji bẹẹ, afi nigba ti awọn ọmọọṣẹ Temitọpẹ to n kọṣẹ yiadirẹsa lọdọ rẹ de ṣọọbu lọjọ Mọnde naa ti wọn ko ba ọga wọn, wọn tilẹ to mẹjọ gẹgẹ ba a ṣe gbọ.

Awọn ọmọ naa pe ọga wọn titi lori foonu, ko gbe e. Wọn pe ọkọ rẹ naa, iyẹn naa ko gbe foonu, ni diẹ ninu wọn ba gba ile baba ọkọ ti wọn mọ lọ lati sọ ohun to n ṣẹlẹ fun un.

Baba naa ni wọn lo mu wọn lọ sile tuntun tọmọ rẹ ko lọ, afi bi wọn ṣe debẹ ti wọn ba ilẹkun ni titi, ti wọn ri ọkada Ismail ninu ile. Bi wọn ṣe n pe foonu awọn tọkọ-taya naa lo n dun ninu ile, ṣugbọn wọn ko gbe e, nibẹ ni awọn to lọọ wo wọn nile ti mọ pe wahala ti wa.

Wọn kọkọ yọju loju windo, wọn ri Ismail atọmọ ẹ lori bẹẹdi, bii pe wọn sun lo ri, bẹẹ ni Tọpẹ wa nilẹẹlẹ ni tiẹ. Nigba ti wọn ja ilẹkun wọle ni wọn ri i pe awọn mẹtẹẹta ti doku, lariwo ba sọ ninu ile, ko si pẹ ti ara adugbo fi gbọ pẹlu, ni kaluku ba n daro ikunlẹ abiyamọ.

Awọn tọkọ-taya yii ni jẹnẹretọ, awọn eeyan kan sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe wọn tan an mọju ni, ki eefin rẹ ma raaye jade daadaa nibi ti wọn gbe e si, wọn lo le jẹ eefin ẹrọ amunawa naa lo pa wọn.

Awọn mi-in ni boya ile tuntun naa lo gbabọde,wọn ni o le jẹ awọn alujannu ti fibẹ ṣebugbe nigba ti wọn ko ti i kọ ọ tan, ti wọn ko si fẹ keeyan waa ba wọn gbebẹ nigba ti wọn pari ile naa tan to ri rekete.

Ko ti i sẹni to lefidi otito iku yii mulẹ titi ta a fi pari iroyin yii, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa lati teṣan Bode-Olude to waa ko awọn oku naa lọ si mọṣuari ọsibitu ijọba, n’Ijaye lawọn yoo ṣe iwadii lori ẹ, ti ayẹwo awọn dokita naa yoo si tun waye pẹlu.

Leave a Reply