Iwọde SARS: A o ni i laju silẹ ki wọn da nnkan ru mọ ijọba lọwọ- Lai Muhammed

Kazeem Ọlajide

Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimo ki ijọba apapọ ma gbe igbesẹ to lagbara lori awọn to n ṣewọde ta ko ẹṣọ SARS atawọn ohun mi-in ti wọn tun n beere fun bayii.

Lopin ọsẹ to kọja yii ni Minisita feto iroyin, Alhaji Lai Mohammed, sọrọ lori telifiṣan nipa iwọde tawọn ọdọ n ṣẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria. O ni ijọba apapọ ko ni i laju ẹ silẹ ki awọn eeyan kan sọ orilẹ-ede yii di rudurudu mọ ọn lọwọ, ti apa ofin ko ni i ka ẹnikẹni mọ.

Minisita yii sọ pe bi awọn eeyan kan ṣe kọlu mọto Gomina ipinlẹ Ọsun, Isiaka Oyetọla, lọsẹ to kọja ti foju han bayii pe awọn janduku kan ti ja iwọde ọhun gba mọ awọn ọdọ ti wọn da a silẹ lọwọ. O ni ọrọ naa ti kuro ni iwọde wọọrọwọ nikan, o ti dohun ti wọn fi n pa ijọba ati araalu lara gididi.

O fi fi kun un pe loootọ lawọn ti wọn da kinni ọhun silẹ le ni ero gidi lọkan, ṣugbọn ohun to n ṣẹlẹ bayii ti foju han pe awọn kọ ni wọn n dari eto ọhun mọ, niṣe lawọn kan ti ja a gba mọ wọn lọwọ, ti ẁọn si n fi ẹhonu ọhun huwa janduku kaakiri

O ni, “Ijọba ti faaye gba araalu pupọ nipa bi a ṣe fun wọn laaye lati fẹhonu han fun odidi ọjọ mọkanla ti wọn ti bẹrẹ si ṣe iwọde kiri, ṣugbọn ti a ba ni ki a wo ohun ti wọn ṣe fun gomina ipinlẹ Ọṣun, a o ri i pe wọn ti n gbe kinni ọhun tayọ aala wọn. Ko si ibikibi lorilẹ agbaye ti ijọba ti maa la oju ẹ silẹ, tawọn eeyan kan maa fi iwọde kan da eto iṣakoso ilu ru mọ ọn lọwọ.

“Ohun to n ṣẹlẹ bayii ti fi han pe ti ijọba ko ba tete gbe igbesẹ to yẹ lati daabobo ẹmi araalu ati dukia, awọn ti wọn ti sọ iwọde yii di nnkan mi-in le da wahala silẹ laarin ilu.” Lai Muhammed lo sọ bẹẹ.

Ko ṣai bu ẹnu atẹ lu bi awọn to n ṣewọde yii ṣe n ti oju popo pa, ti awọn eeyan ko ri ibiiṣẹ wọn lọ, tawọn to si lọ paapaa ko ri aaye pada sile wọn bọrọ. O ni irufẹ nnkan bayii ti di nnkan mi-in, iyẹn ti kuro ni iwọde wọọrọwọ, o ti n bọ si ininilara ati ifiya-jẹ ni ati titẹ ẹtọ ẹlomi-in loju mọlẹ”

O ni ni kete ti wọn bẹrẹ iwọde ọhun ni wọn ti ko koko nnkan marun-un siwaju ijọba, ti ijọba si ti yanju gbogbo ẹ, ṣugbọn dipo ki wọn kuro loju popo, niṣe ni wọn taku, ti wọn si jẹ ki awọn eeyan kan ja a gba mọ wọn lọwọ, ti wọn si fi n di araalu lọwọ bayii.

3 thoughts on “Iwọde SARS: A o ni i laju silẹ ki wọn da nnkan ru mọ ijọba lọwọ- Lai Muhammed

  1. Plz our excellency should address the youth calmly and give them genuine promise that will be fulfilled so that they can go back home solemnly. Pls let peace reign in Nigeria. May God bless Nigeria

  2. Baba e dake isokuso le nso
    Is that the right way to address all the protester including myself .
    E ba ilu je e ni e run Se,ko si apere ilisiwaju kankan fun ilu Nigeria lapapo
    No future for Nigeria youth

  3. Laise aniani ao ri wipe aisi ise nilu, papa fun awon odo, loje ki iwode yi pe bayi, nitori ti gbogbo awon odo wonyi bani ise gidi lowo kole si aye iwode rara. Ni idi eyi ise NLA wafun Ijoba Lati mo ona ati pese ise fun awon odo wonyi.BOJE KI WON BERE LORI “MECHANISE FARMING”.

Leave a Reply