Iwọde ta ko SARS bẹrẹ pada l’Osogbo, Abuja…

Jide Alabi

Bi awọn ọdọ orilẹ-ede yii kan ṣe kede pe ko si ohun to le yẹ ẹ ki iwọde ma bẹrẹ pada lọjọ Aje, Mọnde,  lati fi ta ko aṣilo agbara awọn ẹṣọ agbofinro apa keji, kaakiri awọn ibi kan l’Ekoo, lawọn agbofinro ti wa bayii, ti wọn n sọ pe ki ẹnikẹni ma jade lati gbe patako dani tabi sọ pe awọn n fẹhonu han.

Bi awọn ọlọpaa ṣe wa ni abẹ biriiji Ikẹja, bẹẹ ni wọn wa ni too-geeti Lẹkki, l’Ekoo, ti wọn duro wamu lati koju ẹnikẹni to ba dun pẹkẹn pe oun fẹẹ sewọde.

Pẹlu gbogbo iduro ati imurasilẹ awọn ọlọpaa yii, sibẹ, ALAROYE gbọ pe awọn ọdọ kan ti ko ara wọn jọ bayii l’Abuja.

A tun gbọ pe bẹẹ lọrọ ọhun ri niluu Osogbo, nipinlẹ Ọṣun, bayii, nibi ti wọn ti n fẹhonu han pe wọn gbọdọ tu awọn eeyan awọn ti wọn mu silẹ. Bakan naa ni wọn ni ki banki apapọ ilẹ wa, iyẹn CBN, naa gbẹsẹ kuro lori bo ṣe fofin de gbigba owo ninu apo ikowopamọsi awọn eeyan kan ninu awọn.

Adugbo kan ti wọn n pe ni Ogo-Oluwa, ni wọn ti bẹrẹ iwọde ọhun l’Oṣogbo, ti wọn si gba ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ naa to wa ni Abere lọ.

Akọle ti awọn ọdọ Naijiria yii n gbe kiri ni pe ‘‘awa ko ja fun ẹgbẹ oloṣelu kankan,… opin gbọdọ de ba eto idajọ jakujaku ni Naijiria.’’, ‘‘Ẹ fopin si ayederu igbimọ to n gbọ ẹjọ ta ko ẹṣọ agbofinro SARS l’Ọsun’’, “Ẹ gbẹsẹ kuro lori apo ikowopamọsi awọn eeyan wa’’; ati bẹẹ beẹ lọ lawọn akọle ọhun ṣe lọ loriṣiriiṣi.

Leave a Reply