Ijọba ti din owo-epo bẹtiroolu ku

Faith Adebọla, Eko

Bẹrẹ lati ọjọ kẹrinla, oṣu kejila, ta a wa yii, ijọba apapọ ti kede pe awọn ti din owo-epo bẹntiroolu walẹ, laarin naira mejidinlaaadọsan-an (#168) si naira mejilelaaadọjọ (#162) ni wọn yoo maa ta a bayii.

Minisita fun ọrọ awọn oṣiṣẹ, Chris Ngige, lo kede eyi lowurọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nigba to n jabọ ipade ti wọn ṣe pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ilẹ wa, iyẹn NLC ati TUC.

Ngige ni awọn tun ti gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo tubọ mojuto bi owo-epo ko ṣe ni i maa ṣe segesege, ti yoo si tubọ rọju faraalu.

Lati nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ Aje, Mọnde, lawọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ ọhun ati awọn ti ijọba apapọ ti tilẹkun mọri l’Abuja, lati fori kori lori ọrọ ẹkunwo owo-epo to n ja ranyin nilẹ wa. Nnkan bii aago meji ọganjọ oru nipade too pari.

Titi dasiko yii, nnkan bii aadọsan-an naira (#170) ni wọn n ta jala epo bẹntiroolu, latari bi ẹka ileeṣẹ ijọba to n ṣakoso epo rọbi, NNPC, ṣe buwo le iye tawọn olokoowo yoo maa gbe epo jade loṣu kọkanla to kọja yii, leyii to mu ki ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fariga.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Igbẹjọ Timothy Adegoke: Adedoyin ṣepe fawọn oniroyin ni kootu

Florence Babaṣọla, Oṣogbo Iyalẹnu lo jẹ fawọn oniroyin laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, yii, nigba ti Dokita …

Leave a Reply

//unbeedrillom.com/4/4998019
%d bloggers like this: