Iyanṣẹlodi: A maa da eto idibo ipinlẹ Ọṣun ati Ekiti duro- Ẹgbẹ Akẹkọọ

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Bi ẹgbẹ olukọ awọn ileewe giga fasiti nilẹ wa (ASUU), ṣe fi oṣu mẹta kun iyanṣẹlodi wọn to n lọ lọwọ, ẹgbẹ akẹkọ (NANS), orilẹ-ede yii ti sọ pe awọn ti ṣetan lati mu asorọ ba eto idibo gomina ipinlẹ Ọṣun ati ti Ekiti ti yoo waye ninu oṣu Kẹfa ati Ikeje, ọdun 2022.
Awọn akẹkọọ naa sọ pe gbogbo ohun to ba wa ni ikapa awọn lawọn yoo ṣe lati da eto idibo ipinlẹ Ekiti ati Ọṣun duro, awọn yoo si gbegi di gbogbo ẹnu ọna ajọ eleto idibo nipinlẹ naa.
Wọn tun sọ pe awọn yoo da eto idibo abẹle awọn ẹgbẹ oṣelu to n bọ lọna ru lati fi ẹhonu ati aidunnu awọn han lori iyanṣẹlodi ẹgbẹ olukọ yunifasiti to n lọ lọwọ.
Ninu iwe kan ti ẹgbẹ akẹkọọ naa kọ, eyi ti Alaga wọn Kọmureedi Sunday Aṣẹfọn, fọwọ si to tẹ awọn oniroyin lọwọ niluu Ado-Ekiti l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lo ti sọ pe oṣu mẹta ti wọn fi kun iyanṣẹlodi naa jẹ ọna lati dide ogun si ẹgbẹ akẹkọọ orile-ede yii, ati lati lati doju eto ẹkọ bolẹ.
Ẹgbẹ akẹkọọ naa sọ pe afikun naa tun fi han pe ijọba apapọ ko ṣe ohun kankan lati mojuto irọrun awọn akẹkọọ orilẹ-ede Naijiria, awọn ko si le fara mọ ọn.
Aṣẹfọn ni awọn ti ṣetan lati bẹrẹ eto kan ti wọn pe ni “Operation Test Run” ti wọn yoo ṣe ka gbogbo ẹka wọn to wa ni orilẹ-ede yii ni ọjọ kejila, oṣu Karun-un, ọdun 2022. O ni wọn yoo di gbogbo ọna to ṣe pataki ni gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji ati ilu Abuja pa.
“Gbogbo ọna ni ẹgbẹ akẹkọ yoo gba lati ri i pe ijọba apapọ yanju ọrọ naa, ṣugbọn ni bayii, lorukọ gbogbo ẹgbẹ akẹkọ orile-ede yii, a ti gbe pẹrẹgi ija kana pẹlu ijoba apapọ.
“Iwọde ti a fẹẹ ṣe yoo waye ni gbogbo ipinlẹ to wa lorilẹ-ede yii, gbogbo ọna to wa lorileede yii ni a maa pa igi di fun wakati mẹta gbako lojoojumọ.
‘‘Lẹyin eyi ni gbogbo ẹgbẹ akẹkọọ yoo ṣe ipade kan ti yoo waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinla, oṣun Karun-un, ọdun 2022.
“A fi asiko yii sọ fun awọn agbofinro ki wọn ma ṣe da wa duro lakooko iwọde ati ifẹhonu han naa.’’

Leave a Reply