Iyanṣẹlodi: Awọn dokita ipinlẹ Kwara dara pọ mọ awọn ẹlẹgbẹ wọn

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Aje, Monde, ọṣẹ yii, lawọn dokita nileewosan olukọni Fasiti tilu Ilọrin, (UITH) nipinlẹ Kwara, dara pọ mọ ẹgbẹ awọn dokita nilẹ yii, ti wọn si gun le iyansẹlodi gẹgẹ bi aṣẹ ti ṣe waa latoke, latari pe ijọba apapọ ko dahun si awọn ibeere wọn, ṣugbọn awọn dokita agba ti wọn n pe ni (Consultant) ko jẹ ki iṣẹ duro, wọn n ṣe itọju awọn alaisan lọ ni tiwọn.

Lara awọn oṣiṣẹ ileewosan naa to ba oniroyin wa sọrọ sọ pe ootọ ni pe awọn dokita da iṣẹ silẹ, tori pe gbogbo ipinlẹ to wa ni abẹ orile-ede Naijiria ni ọrọ naa kan, ohun to ba si de ba oju, dandan ni ko de ba imu. O ni oun fi da wa loju pe dida iṣẹ silẹ naa ko di iṣẹ lọwọ ni ileewosan tawọn rara, awọn agba dokita n da awọn alaisan loun, ti gbogbo eto si n lọ bo ti tọ ati bo ti yẹ.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe ẹgbẹ awọn dokita ti fun ijọba ni akoko, ki ijọba naa ṣe ohun to yẹ lori ibeere awọn, ati pe awọn ti kọkọ da isẹ silẹ tẹlẹ, ṣugbọn awọn fun ijọba ni anfaani lẹẹkeji, awọn wọsẹ pada, latigba naa, ijọba ko gbe igbesẹ kankan, eyi lo fa a tawọn fi gun le iyanṣẹlodi pada, nigba to jẹ pe ede ti ijọba gbọ niyẹn.

 

 

Leave a Reply