Faith Adebọla, Eko
Ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa n’Igando ti fopin si igbeyawo ọdun mẹẹẹdogun kan lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, iyaale ile ẹni ọdun mẹrinlelogoji kan, Rebecca Adeniyi, lo loun o nifẹẹ ọkọ oun, Yusuf Adeniyi, ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta mọ, tori agbere ọkunrin naa kọja ohun ti oun le fara da, ki nnkan mi-in ma lọọ ṣẹlẹ.
Olupẹjọ naa ṣalaye ni kootu pe iwa ṣina ṣiṣe wọ ọkọ oun lẹwu debii pe oun ka a mọ ori ale lọjọ kan, ihooho goloto lawọn mejeeji wa, ori ara wọn loun si ba wọn ti wọn n laṣepọ.
O ni lati ọjọ naa lọkan oun ti yọ pata ninu igbeyawo awọn, tori niṣe lọkunrin naa n run bii igbẹ soun latigba naa, Bẹẹ ṣaaju akoko yii, eti oun ti kun nigboro fun iwa palapala ti wọn n sọ foun pe ọkọ oun n hu pẹlu awọn obinrin olobinrin, to fi mọ awọn iyawo ile ẹlomi-in.
O ni loootọ ni Yusuf bẹ oun lọjọ toun ka wọn mọ, to ni koun ma taṣiiri ale naa, ṣugbọn latigba naa ni iwa rẹ ti yipada soun, ko ki i foun lowo ounjẹ mọ, ko si gbọ bukaata ninu ile, niṣe lo n kanra bii aja elekuru, inu oun ko si dun si i mọ, ifẹ ẹ ti domi lọkan oun.
O tun fẹsun kan ọkọ ẹ pe oogun abẹnugọngọ lo fi fẹ oun, kinni naa si ti ka kuro loju oun lati ọdun marun-un sẹyin.
Nigba ti wọn ni ki Yusuf fesi si ẹsun tiyawo ẹ fi kan an, o ni oun gbọdọ so ootọ, ko si irọ ninu ẹjọ tiyawo oun ro, loootọ lo ka oun mọ ori ale lori bẹẹdi awọn, ṣugbọn oun ti bẹ ẹ, o si loun ti gbọ, eyi lo mu koun ro pe ọrọ naa ti pari sibẹ.
Ni ti ẹsun oogun abẹnugọngọ, olujẹjọ ni ko si ohun to jọ bẹẹ, iyawo oun lo n ṣe oogun, tori oun mọ pe o maa n lọ sọdọ awọn babalawo kan, eyi lo si jẹ ki iwa oun yipada si i.
Lẹyin atotonu awọn mejeeji, Adajọ Adeniyi Kọledoye to jẹ Aarẹ kootu naa sọ pe ẹri to wa niwaju oun fihan pe ko si ifẹ mọ laarin olupẹjọ ati olujẹjọ naa.
“Ile-ẹjọ yii ko ni nnkan mi-in lati ṣe ju ka fọwọ si ẹbẹ olupẹjọ. Nitori naa, lati akoko yii lọ, ile-ẹjọ yii tu igbeyawo to wa laarin Abilekọ Rebecca Adeniyi ati Yusuf Adeniyi ka, ẹyin mejeeji ki i ṣe tọkọ-taya mọ”. Bẹẹ ni adajọ kede.