Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn Yoruba maa n gbadura kan, wọn aa ni ki Ọlọrun ma jẹ ka ku akurun. Idi si ree ti wọn ṣe maa n dena ohunkohun to ba le fa ijamba ina tabi ijamba ọkọ lasiko ti wọn ba n rinrin-ajo pẹlu gbogbo idile wọn. Ṣugbọn ni ti baale ile kan to n jẹ Ahmed Saka, funra rẹ lo dana sun iyawo atawọn ọmọ ẹ, ti gbogbo wọn si ku akurun sinu ile wọn to wa laduugbo Ṣogoye, n’Ibadan.
Ki i ṣe pe ọkunrin naa ya were, ifẹ lo ṣe bii ẹni fẹẹ da a lori ru, kíkọ̀ ti Mutiat iyawo rẹ kọ ọ silẹ lo da a a ni laakaye ru, lo ba binu sun ololufẹ ẹ nina pẹlu awọn ọmọ lalẹ ọjọ keje, oṣu kẹrin, ọdun 2021, ti i ṣe Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Eeyan mẹrin mi-in lo tun fara ṣeṣe ninu iṣẹlẹ naa, to je pe Ọlọrun ni ko pa wọn.
Iku gbigbona ọhun ko da oun paapaa si, epo bẹtiroolu to fi dana sun iyawo ẹ gbana mọ oun paapaa lara, ti ina si jo oun naa pa lẹyin ti gbogbo ohun to gboju le laye ti jona tan.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lẹnu ọjọ mẹta yii ni gbọnmi-si-i-omi-o-to-o waye laarin Ahmed pẹlu iyawo ẹ. Eyi lo mu ki obinrin naa sọ fun un pe oun ko fẹ ẹ mọ. Ihalẹ lasan ni Mutiat pe e nigba ti Ahmed sọ pe oun yoo pa a danu to ba gbe iru igbesẹ bẹẹ, ti obinrin naa si fesi pe bo ba wu u, ko fori sọlẹ, nnkan ti oun yoo ṣe loun ti sọ fun un yẹn, afigba ti awọn mejeeji mu ileri wọn ṣẹ, ti wọn si fi ọrọ ara tiwọn ko ba awọn ọmọ mejeeji ti wọn bi funra wọn.
Orukọ awọn ọmọ ọhun ni Ramon Sarumi, ọmọọdun mẹwaa, ati Abiọdun Ọladele to jẹ ọmọ ọdun meje.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi sọ pe ni kete ti awọn alabaagbe idile Ahmed laduugbo Ṣogoye ti fi iṣẹlẹ ọhun to wọn leti lawọn agbofinro ti lọ sibẹ lati ṣewadii iṣẹlẹ naa.
O ni ileewosan ti wọn n pe ni Anglican Diocese Hospital, laduugbo Mọlete, n’Ibadan, ni wọn gbe awọn mẹrẹẹrin ti wọn fara pa ninu ijamba naa lọ fun itọju.