Jamiu ba aṣẹwo lo pọ tan, lo ba gun un lọbẹ pa l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Jamiu Malọmọ lọmọkunrin yii n jẹ, ọmọ ọdun mejidinlogun pere ni (18), ṣugbọn ni bayii, o ti wa lẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ awọn apaayan nipinlẹ Ogun, nitori niṣe lo gun aṣẹwo to ba lo pọ lọbẹ lọrun, o si ri i daju pe o ku patapata.

Ohun to ṣẹlẹ gan-an gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣe fi to wa leti ni pe lọjọ kejidinlogun, oṣu keje, ọdun 2021 yii, Alaga agbegbe Ilupeju, Oke-Arẹgba, mu ẹjọ lọ si teṣan ọlọpaa Adatan, pe niṣe lawọn ji ba oku ọmọbinrin kan lori apata to wa lagbegbe naa. O ni oju ibi ti wọn ti gun obinrin naa lọbẹ han ketekete, ọbẹ ti wọn si fi gun un pa naa wa lẹgbẹẹ rẹ nibẹ to kun fun ẹjẹ.

Awọn ọlọpaa lọọ gbe oku naa, wọn gbe e lọ si mọṣuari ijọba to wa n’Ijaye, l’Abẹokuta. Lẹyin eyi ni wọn bẹrẹ iwadii to lagbara lati mọ ẹni to ku yii, ati bo ṣe rin irin ẹ to fi pari ẹ sori apata.

Ninu iwadii ni wọn ti ri i daju pe ọmọkunrin yii, Jamiu Malọmọ, ni awọn eeyan ri gbẹyin pẹlu oloogbe naa. Ọjọbọ ti i ṣe ọjọ kejilelogun, oṣu keje, lọwọ si ba a nibi ile ọti kan to wa ni Panṣẹkẹ, l’Abẹokuta.

Niṣe lo tiẹ tun fẹẹ gbe aṣẹwo mi-in nibi ti wọn ti mu un naa, iyẹn ni nnkan bii aago mejila oru ku iṣẹju mẹẹẹdogun.

 Nigba ti wọn mu un tan ti wọn si bẹrẹ si i da ibeere bo o, ọmọ ọdun mejidinlogun yii jẹwọ ohun to ṣe. 

Jamiu ṣalaye fawọn ọlọpaa pe oloṣo lọmọ to doloogbe yii, Azeezat Akande lo n jẹ. O ni oun gbe e lọ sile lọjọ naa lati ba a sun, iyẹn lẹyin tawọn pari ọrọ si ẹgbẹrun mẹwaa naira owo ibasun naa.

Ọmọkunrin yii ṣalaye pe nigba toun ba a sun tan, aṣẹwo naa beere owo rẹ, oun si ko ẹgbẹrun mẹjọ naira fun un dipo mẹwaa tawọn jọ sọ koun too ba a ṣe pọ.

O ni oloṣo naa yari pe afi kowo oun pe, eyi si di ariyanjiyan laarin awọn, eyi lo jẹ koun mu foonu oun fun un pe ko mu un dani na, ko si duro de oun loju ọna tawọn jọ wa lasiko toun fun un lowo naa, koun lọọ ba a mu ẹgbẹrun meji to ku wa nile.

Nibi ti Azeezat ti n duro de e ni Jamiu ti de ẹyin rẹ lojiji, o si fi ọbẹ gun un lọrun to jẹ niṣe lọmọbinrin naa ku lẹsẹkẹsẹ. Bo ti huwa laabi naa tan lo sa lọ.

Ṣugbọn nigba tọwọ ọlọpaa ti tẹ ẹ bayii, ọmọdekunrin yii ti wa lẹka awọn ti wọn fẹsun ipaniyan kan, ẹjọ ti yoo si lọọ jẹ ni kootu laipẹ naa niyẹn.

Leave a Reply