Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Arakunrin kan, Umoru Jidah, ti n kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ bayii. Ẹsun pe o pe Arabinrin Khadija ni ajẹ, lo ba lọọ pade ẹ ninu igbo, o si fọgi mọ ọn lori titi tiyẹn fi ku patapata niluu Gwanara, nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara, ni wọn tori ẹ wọ ọ lọ siwaju ile-ẹjọ Magistreeti kan niluu Ilọrin, fun ẹsun ipaniyan.
Ẹgbọn oloogbe, Mohammed Aliyu, lo mu ẹsun lọ si ọfiisi ajọ sifu difẹnsi pe wọn n wa aburo rẹ, Khadija, sugbọn nigba ti ọwọ ọlọpaa tẹ Jẹdah ti iwadii n lọ lọwọ, o jẹwọ pe loootọ loun ṣeku pa Khadija, ati pe ajẹ ni ọmọbinrin naa, o si fi ajẹ rẹ pa aburo iyawo oun, iyẹn Hassana.
Onidaajọ Mohammed, ti ni ki wọn ju Jidah si ọgba ẹwọn, o sun igbẹjọ miiran si ọjọ kọkanlelogun, ọsu Karun-un, ọdun yii.