Joshua ati Fury ti ṣetan lati ja nigba meji – Eddie Hearn

Oluyinka Soyemi

Gbajugbaja eleto ẹṣẹ kikan, Eddie Hearn, ti kede pe Anthony Joshua ati Tyson Fury ti ṣetan lati ja nigba meji, eto si ti n lọ lọwọ.

Eddie sọ ọ di mimọ pe awọn mejeeji ti gba lati gbe igbesẹ naa ki wọn le ja ija to lagbara ju ninu itan ẹṣẹ kikan lagbaaye.

Ibi tawọn ija naa yoo ti waye atawọn eto mi-in ti n lọ lọwọ, o si ṣee ṣe ko jẹ ọdun 2021 ni yoo waye nitori Joshua gbọdọ kọkọ ja pẹlu Oleksandr Usyk tabi ẹlomi-in, nigba to ṣee ṣe ki Fury ati Deontay Wilder tun pade.

Ami-ẹyẹ WBA, IBF ati WBO ati IBO lo wa lọwọ Joshua, nigba ti Fury di WBC mu lẹyin to fiya jẹ Wilder ilẹ Amẹrica loṣu keji, ọdun yii.

Fury ni gbogbo awọn bẹliiti yii wa lọwọ ẹ tẹlẹ, ṣugbọn awọn alaṣẹ gba a lọwọ ẹ lọdun 2015 nitori wahala ilera to ni.

Ọmọ England ni Joshua ati Fury, eyi to tumọ si pe ilẹ naa ni gbogbo bẹliiti to gbajumọ ju lagbo ẹṣẹ kikan wa lọwọlọwọ.

Tẹ o ba gbagbe, ija mẹrinlelogun ni Joshua ti ja, ẹẹkan pere lo si fidi-rẹmi. Ija mọkanlelọgbọn ni Fury ti ja ni tiẹ, ko si fidi-rẹmi ri.

Leave a Reply