Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti kede pe awọn ti pese aabo to peye si gbogbo tibu tooro ipinlẹ Kwara, ki awọn eeyan jade lọ sibi to wu wọn ni ọjọ Abamẹta ti i ṣe ayajọ ọjọ awa-ara-wa.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ. Ọkasanmi ni iroyin ti de si etiigbọ awọn pe ibẹru bojo ti gbilẹ nipinlẹ naa latari iwọde ti awọn kan n dunkooko pe awọn fẹẹ ṣe. O tẹsiwaju pe ko sohun to jọ ọ pe awọn ti ni ẹnikankan ko gbọdọ jade lọla, iroyin ofege lasan ni.
O waa rọ gbogbo ọmọ Kwara lati gba alaafia laaye, ki wọn ṣe ayẹyẹ naa pẹlu ifẹ ati iṣọkan, ki wọn si yago fun iwa janduku to le da omi alaafia ilu ru.