Faith Adebọla
Ẹlẹkọ ọrun to n polowo nipinlẹ Kaduna lasiko yii ko sinmi rara, niṣe nipinlẹ naa n gbona girigiri, pẹlu bawọn agbebọn ṣe tun ṣeku pa eeyan mẹẹẹdogun mi-in loru ọjọ Aiku, Sannde, si owurọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹta yii.
Pẹlu iṣẹlẹ yii, o ti di ẹẹmẹta ọtọọtọ tawọn afẹmiṣofo naa ti ṣakọlu si ipinlẹ ọhun laarin ọjọ mẹwaa pere, ti wọn si ti fẹmi eeyan to ju ọgọrin (80) lọ ṣofo, ọpọ awọn to fara pa ṣi wa lawọn ọsibitu kaakiri ipinlẹ naa di ba a ṣe n sọ yii.
Akọlu to waye laaarọ ọjọ Aje yii, abule Hanyin Kanwa, to wa lagbegbe Yakawada, nijọba ibilẹ Giwa, nipinlẹ Kaduna, lo ti ṣẹlẹ.
Bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa ṣe wi, ọganjọ oru lawọn agbebọn naa ya bo awọn ara abule naa, niṣe ni wọn yi i po, ti wọn si n yinbọn lu gbogbo awọn ti wọn n sun lọwọ, bi wọn ṣe n pa wọn ni wọn n dana sun ile ati dukia wọn.
Nigba tilẹ yoo fi mọ, oku eeyan mẹẹẹdogun ni wọn ri ṣa jọ, wọn si sin wọn tẹkun-tomije, nilana ẹsin Musulumi.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ṣugbọn wọn lawọn o ti i le sọ pato iye eeyan to doloogbe ninu akọlu ọhun.
Tẹ o ba gbagbe, eeyan marundinlogoji lawọn afẹmiṣofo yii ṣeku pa loru mọju ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta yii, kan naa, nijọba ibilẹ Giwa ọhun.
Bakan naa ni ipakupa rẹpẹtẹ kan ti waye lọjọ marun-un ṣaaju eyi, ninu eyi ti wọn ti fẹmi eeyan to din diẹ laaadọta ṣofo.