Kayeefi ree o, lọjọ keji ti kọmiṣanna yii darapọ mọ ẹgbẹ APC lati PDP lọmọ rẹ fo ṣanlẹ to ku ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ keji ti kọmiṣanna tẹlẹ, to tun jẹ alaga igbimọ alakooso ni ileewe gbogbonise ipinlẹ Kwara (Kwara State Polytechnic) tẹlẹ, Onimọ ẹrọ Ayinla Musa Yeketi, kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, to si darapọ mọ APC ni ọmọ rẹ ọkunrin, Nafiu Ayinla Yeketi, ku lojiji.

Lọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, ni kọmiṣanna tẹlẹ ọhun n ṣe ayẹyẹ igbeyawo ọkan lara awọn ọmọ rẹ, ọjọ yii kan naa lo kede pe oun o ṣe ẹgbẹ oṣelu PDP mọ, o ni ninu ẹgbẹ APC ni ọjọ ọla rere awọn olugbe ipinlẹ Kwara wa, fun idi eyi, oun ti fi PDP silẹ bii ọsan amuku, oun si ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Onitẹsiwaju (APC).

Bo tilẹ jẹ pe oniruuru awuyewuye lo ti waye lori bo ṣe fi ẹgbẹ naa silẹ, nitori awọn kan sọ pe o ti gbowo lọwọ Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq , ni.

Alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni wọn kede iku ọmọ rẹ, Nafiu, ti wọn jọ ṣe ayẹyẹ igbeyawo lọjọ Aiku, Sannde. ALAROYE, gbọ pe ọjọ Aje ni ọmọkunrin naa gun baaluu pada si ipinlẹ Eko to n gbe, nibi to ti n ṣiṣẹ aje rẹ, ti wọn si kede iku rẹ ni ọjọ yii kan naa.

Owuyẹ kan sọ pe fun ra ẹ lo gbe majele jẹ, to si wa mọto lọ sileewosan kan ti wọn ko darukọ niluu Eko. Funra rẹ lo sọ fun dokita pe oun ti gbe majele jẹ, to si gbabẹ ku.

Ṣugbọn awọn mọlẹbi ko sọ iru iku to pa ọmọ naa titi di asiko yii.

Leave a Reply