Ki laa ti waa ṣeyi si, awọn Fulani tun pa agbẹ meji n’Igangan

Ọlawale Ajao, Ibadan

O kere tan, eeyan meji lo ku, tọpọ eeyan si fara pa nigba ti awọn Fulani agbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ, tun  kọ lu awọn agbẹ niluu Igangan, nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee.

ALAROYE gbọ pe niṣe lawọn Fulani to filu Igangan ṣebugbe ọhun lọọ da awọn agbẹ to n ti inu oko wọn bọ lọna, ti wọn si pa meji ninu wọn loju-ẹsẹ.

Iroyin awọn iṣẹlẹ to ni i ṣe pẹlu iroyin ìṣekúpani, ijinigbe ati ìkọlù lo n ti agbegbe Oke-Ogun jade lẹnu ọjọ mẹta yii, paapaa lawọn ilu bii Igboọra, Igangan, Iganna, Idere, Ayetẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ. Awọn Fulani lawọn ara agbegbe naa si maa n tọka si gẹgẹ bii afurasi ọdaran lọpọlọpọ igba ti awọn iṣẹlẹ ibanujẹ bẹẹ ba waye.

Eyi la gbọ pe o mu ki akinkanju ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeeyan mọ si Sunday Igboho, lọọ ṣabẹwo si Seriki Fulani ti Igangan, Ọgbẹni Saliu Kadiri, lati ba awọn eeyan ẹ sọrọ pe ki wọn dẹ́kun ijinigbe ati pipa ti wọn n pa awọn Yoruba nilẹ baba wọn.

Gẹgẹ bi oludari ẹgbẹ to n ja fun idagbasoke ilẹ Igangan, Ọladiran Ọladokun, ṣe fidi ẹ mulẹ, o ni “Sunday Igboho wa si Igangan lati dẹkun awọn iwa ọdaran ti awọn Fulani maa n hu. O kọkọ lọ si ọja Kaara, nitori inu ọja yẹn lawọn Fulani wọnyẹn ti saaba maa n ṣe awọn laabi wọn. Nitori ẹ lawọn kan ṣe n sọ pe ki ijọba ti ọja yẹn pa.

“Lẹyin naa lo lọ si aafin Seriki Fulani, to si sọ fun un pe oun ko gbọdọ gbọ pe awọn Fulani tun pa Yoruba nibi kankan mọ, nitori naa, ko yaa kilọ fun awọn eeyan ẹ daadaa.”

Igbesẹ ti Sunday Igboho gbe yii la gbọ pe awọn Fulani kan ninu ilu naa ka si iwa arifin si ọba wọn, ti wọn fi lọọ kọ lu awọn agbẹ to n lọ sile jẹẹjẹ wọn nirọlẹ ọjọ Ẹti ọhun, ti wọn si pa meji ninu wọn da sọna oko.

Nigba ti akọroyin wa pe Ọgbẹni Dapọ Salami ti i ṣe oludamọran fun Sunday Igboho lori ẹrọ ibanisọrọ, ọkunrin naa ṣalaye pe ‘‘Loootọ l’Alayé (Igboho) lọ si Igangan lati lọọ ba Seriki Fulani ibẹ sọrọ. Ko si si ọrọ pupọ naa nibẹ ju ikilọ lọ.

“Wọn kilọ fun Seriki Fulani lati ba awọn eeyan ẹ sọrọ, pe dùǹdú awọn Fulani ti n láta ju nilẹ Yoruba. Bawo lawọn ajeji ṣe le maa ji wa gbe, ti wọn yoo maa pa wa nilẹ baba wa. Wọn ni ki Seriki kilọ fawọn eeyan ẹ ki wọn so ewé agbéjẹ́ẹ́ mọ́wọ́.

“Lẹyin ti wọn (Igboho) kuro n’Igangan tan la gbọ pe awọn Fulani ko ibọn ati ada jade, ti wọn si pa ọmọ Yoruba meji. Njẹ o yẹ ki awọn Fulani le maa gbe ibọn ati ada rin bo ṣe wu wọn nigba ti ko si anfaani iru ẹ fun awa ta a nìlú nitori pe ofin orileede yii ko faaye ẹ silẹ?’’

Leave a Reply