‘Kinni’ ọlọpaa dun mọ Mariam, lo ba kọ ọkọ ẹ silẹ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Owe awọn agba kan lo sọ pe tojú bọlé ló mọ ibi ọbẹ̀ ti dùn. Awọn Yoruba yii kan naa ni wọn powe mi-in pe bọ́mọdé ba róyin a sàkàrà nù. Ati ikinni ati ikeji owe yii lo ṣe wẹ́kú mọ iyawo ile kan lara pẹlu bo ṣe deede kọ ọkọ ẹ silẹ lẹyin to ti tọ́ kinni ọlọpaa wo, to si ri i pe o dun ju tọkọ oun lọ.

Ọdun kejila ree ti obinrin yii, Mariam Adewọyin, pẹlu ọkọ ẹ, Saheed Adewọyin, ti ṣegbeyawo. Ṣugbọn lati bii ọdun meji ti obinrin oniṣowo yii ti bẹrẹ si i yan ọlọpaa lale, to si ti n tọ kondo ọlọpaa wo, to ri i pe kinni ọhun dun labẹ ju ti ọlọkada to gbe oun sile lọ, ni igbeyawo ọhun ti fori ṣanpọn.

Gẹgẹ bii iwadii ALAROYE, nigba ti Mariam kọkọ pade agbofinro, ti  iyẹn ti n la kondo nla mọ ọn labẹ, lo ti bẹrẹ si i fi ọkọ ẹ ṣe faari nigbakuugba ti iyẹn ba fi oorun lọ ọ gẹgẹ bii ololufẹ. Ṣugbọn nigba ti kinni ọlọpaa dun mọ ọn pata, niṣe lo kuku yari fun ọkọ ẹ kanlẹ, o loun ko le fara oun silẹ fun un mọ, nitori oun ko gbadun kinni ẹ mọ o jare.

Ṣugbọn bo ṣe wà ní lìkì, bẹ́ẹ̀ náà ló wà ní gbàǹja. Bi kinni agbofinro ṣe da ile ọlọkada ru ni tobinrin oniṣowo yii paapaa da ile ọlọpaa ru. Ọkunrin ta a forukọ bo laṣiiri yii naa ti niyawo atawọn ọmọ nile, ṣugbọn lati igba to ti ṣalabaapade Mariam lo ti pa iyawo atawọn ọmọ ẹ ti patapata, ṣe wọn ko kuku jọ gbe papọ tẹlẹ, owo lo fi n ranṣẹ si wọn lati maa fi jẹun ni tiwọn. Iyawo oniyawo to mọ ere e ṣe daadaa lo ku to n fi aaye silẹ fun lojoojumọ.

Bi ọrọ ba fara sin ní kọ̀kọ̀ títí, bó pẹ́ bó ya, a máa jáde sí gbangba. Awọn ololufẹ ikọkọ yii ba ọrọ ara wọn debi ti aṣiri wọn tu si ọkọ iyawo lọwọ. Iyẹn sọ ọ dija, o si lọọ fẹjọ ọga políìsì sun awọn agbofinro ẹgbẹ ẹ ki wọn le da a lẹkun iwa ibajẹ to n hu.

Ko pẹ ko jinna ni wọn gbe agbofinro yii kuro n’Ibadan, o di jùà, niluu Ìgànnà, lagbegbe Oke-Ogun, ni ipinlẹ Ọyọ kan naa. Ṣugbọn kaka ki eyi jẹ oore-ọfẹ fun Saheed lati gbadun iyawo ẹ, nnkan ibanujẹ lo tun jẹ nitori niṣe niṣẹlẹ naa mu un padanu obinrin naa patapata.

 

Idi ni pe bi wọn ṣe gbe ale iyawo ẹ lọ si ilu to jinna yii lọkunrin agbofinro naa ti n ronu bi oun ko ṣe ni i padanu adun to n ri lara iyawo oniyawo. Awọn mejeeji jọ gbadun ara wọn ju ololufẹ kaluku wọn lọ ni.

 

Aṣẹyinwa aṣẹyinbọ, iyawo ọlọkada to ti bimọ mẹta s’Ibadan sa ba ọga políìsì lọ. Lasiko yii, awọn mejeeji ko ṣe ọrọ ifẹ wọn ni bòńkẹ́lẹ́ mọ, wọn kuku ṣegbeyawo alarinrin niluu Ìgànnà ti iṣẹ ijọba gbe ale to pada di ojulowo ọkọ lọ.

Iya ọlọmọ mẹta n’Ibadan pada di iyawo aṣẹṣẹgbe ti wọn n fi oju ọmọge wo n’Ígànnà, ko kuku si ẹni to mọ pe o ti bimọ ri, oun naa ko si sọ fẹnikan pe iyawo to ti ni iriri ọpọlọpọ ọdun lọọdẹ ọkunrin kan n’Ibadan ri loun yatọ si ọkọ rẹ tuntun to mọ gbogbo bo ṣe n lọ.

Ni bayii ti iyawo tuntun n’Ígàngán ti n gbadun oorun bo ṣe wu u pẹlu ọkọ ẹ, ko fẹ ohunkohun to le da igbadun ọhun duro mọ bo ti wù kó mọ. N lo ba gba kootu ibilẹ Ọja’ba, n’Ibadan lọ, o loun fẹẹ kọ ọkọ oun aarọ silẹ, ki ile-ẹjọ ba oun fopin si igbeyawo ọlọdun mejila to wa laarin awọn.

Awijare olupẹjọ ni kootu ni pe olujẹjọ ki i tọju oun, ati pe ija lawọn maa n ja ṣaa lojoojumọ.

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ọdaju ọkunrin ni. Ki i tọju mi rara.  Mo jẹ ẹnikan lowo, ọkọ mi waa lọọ sọ fun ẹni yẹn  pe ko ja mi sihooho. Iya ẹ naa mọ nipa ọrọ yii, wọn jọ gbimọ-pọ pẹlu awọn to ja mi sihooho ni. Nibi ti mo ti n gbowo lọwọ ẹni ti mo tajà fun lọwọ ni wọn ti ja mi sihooho nita gbangba.

“Iṣẹlẹ yẹn wa lara idi to jẹ ki n kuro nile ẹ fun ọdun kan ati oṣu mẹjọ. Abikẹyin wa nikan ni mo gbe dání lọ, awọn mejeeji ta a bi ṣaaju nikan ni mo fi silẹ pẹlu ẹ. Igba Naira (N200) lo si n fun mi gẹgẹ bii owo ounjẹ ọmọ to wa lọdọ mi lojumọ.

“O maa n bẹ mi pe ki n pada sile oun nitori awọn ọmọ. Mo pada sibẹ ninu oṣu karun-un, ọdun yii, ṣugbọn gbogbo ẹru mi lo ti ta tan ki n too de.

“Gbogbo ọna lo n wa ki n fi loyun foun lẹyin ti mo pada de, ṣugbọn mi o jẹ ki ọrọ oyun waye. Nitori pe mo kọ lati loyun fun un lo ṣe n sọ pe mo n yan ọlọpaa lale.”

Olupẹjọ waa rọ ile-ẹjọ naa lati fopin si ibaṣepọ to wa laarin oun ati ọlọkada naa nitori ifẹ ẹ ti yọ kuro lọkan oun patapata. Bẹẹ lo sọ pe oun fara mọ kile-ẹjọ yọnda itọju awọn ọmọ mẹtẹẹta ti oun bi fun baba wọn.

 

Gegẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, nigba ti awọn ẹbi ọkọ gbọ pe iyawo awọn ti ṣegbeyawo bonkẹlẹ pẹlu ọlọpaa lẹyin odi ni wọn gbe igbesẹ lati da sẹria fun un, ti wọn si ja a sihooho nita gbangba.

Ọkan ninu awọn ẹgbọn Saheed, ẹni to fara han nile-ejọ lati jẹrii ta ko olupẹjọ sọ pe iya awọn ko mọ nipa bi wọn ṣe ja Mariam sihooho. Ṣugbọn oun lo oore-ọfẹ ihoho ti wọn ja a si ọhun lati gba ẹrọ ibanisọrọ rẹ lọwọ ẹ nitori o jẹ oun lẹgbẹrun marundinlaaadọta Naira (N45,000).

Obinrin oniṣowo yii sọ pe nitori owo ti iyawo aburo oun ya lọwọ oun, ṣugbọn to kọ lati da pada yii  loun ṣe gba foonu ẹ, oore-ọfẹ asiko ti wọn ja a sihooho yii loun lo lati gba foonu lọwọ ẹ titi digba ti yoo fi sanwo gbese to jẹ oun

Ninu ọrọ tiẹ, Saheed sọ pe oun fara mọ kile-ẹjọ fopin si ibaṣepọ oun ati olupẹjọ nitori obinrin naa ki i ṣe obinrin ti wọn n firu ẹ tọrọ niyawo.

Ọkunrin ọlọkada yii ṣalaye pe “Baba nla oniranu lobinrin tẹ ẹ n wo yii. Ọlọpaa lo n yan lale. Koda, mo ti ka awọn mejeeji mọ ori ara wọn ri. Lanlọọdu ọlọpaa yẹn gan-an ti lu mi nigba ti mo sọ ọrọ yẹn di wahala ko too mọ pe iyawo mi ni tẹnanti oun n ba laṣepọ.

“Mo fẹjọ ọlọpaa yẹn sun lagọọ ọlọpaa. Ẹyin igba yẹn ni wọn gbe e lọ siluu Iganna, to si lọọ ṣegbeyawo pẹlu iyawo mi nibẹ.

“Ohun to tiẹ maa n dun mi ni bi iyawo mi ṣe maa n fi ale rẹ halẹ mọ mi. Aa ni ọrẹ oun ọlọpaa ti di mòpóòlù, ki n jẹ ma ṣe mọnamọna pẹlu ẹ ko ma lọọ yinbọn pa mi.”

O ni oun fara mọ kile-ẹjọ tu igbeyawo oun pẹlu obinrin naa ka, ṣugbọn ki wọn ma gba a laye lati mu awọn ọmọ sọdọ, nitori ki i ṣe obinrin to raaye ọrọ ọmọ rara.

Ninu idajọ wọn, igbimọ awọn adajọ kootu naa, labẹ akoso Oloye Ọdunade Ademọla, Alhaji Suleiman Apanpa ati Alhaji Rafiu Raji ti fopin si igbeyawo ọlọdun mejila to seso ọmọ mẹta naa.

Olujẹjọ ni wọn yọnda awọn ọmọ wọn mẹtẹẹta fun. Ṣugbọn wọn ni ko san ẹgbẹrun meji Naira (N2,000) fun olupẹjọ lati ko ẹru rẹ lọ sibi to ba fẹẹ lọ nigboro ilu Ibadan.

Leave a Reply