Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo tilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọ pe o digba ti ijiya nla ba wa fun ẹnikẹni to ba huwa ọdaran lorileede yii ki gbogbo eeyan too le fẹdọ leri orooro.
Nibi apero alaafia kan ti Ọba Akanbi ṣagbekalẹ rẹ laarin awọn Fulani darandaran ilu Iwo atawọn agbẹ lo ti sọ pe gbogbo wahala ti orileede yii n koju ko ṣẹyin bi pupọ ninu awọn ẹlẹṣẹ ṣe maa n lọ lai jiya.
O ni tijọba ba bẹrẹ si i fiya to tọ jẹ awọn ọdaran, ti wọn dajọ iku fun ẹni to ba paayan lai fi ti ẹya to ti wa tabi ti ede to n sọ ṣe, ti ajinigbe n gba idajọ iku, ti ẹnikẹni to ba kowo ilu jẹ n gba idajọ tirẹ, nigba naa ni iwa ọdaran yoo dinku patapata lorileede Naijiria.
Lati le mu ki eyi rọrun, Oluwoo ke sijọba apapọ lati ṣedasilẹ awọn ọlọpaa agbegbe, iyẹn State Police, o ni ki onikaluku maa ṣọdẹ agbegbe rẹ, ki awọn ọlọpaa ti wọn jẹ ọmọ Yoruba maa ṣọ ilẹ Yoruba, ki awọn to jẹ Ibo maa ṣọ agbegbe wọn, ki awọn Hausa naa maa ṣọ agbegbe wọn ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O ṣalaye pe nipasẹ eleyii, ko si ọdaran kankan ti yoo nira lati tete da mọ ati lati mọ ibi to ti wa, bẹẹ ni ọwọ ofin yoo si tete maa ba wọn, ti wọn yoo si foju winna ofin.
Ọba Adewale ni ijọba gbọdọ ṣetan lati gba ọkẹ aimọye awọn ọdọ si iṣẹ ọlọpaa lati le din wahala eto aabo ku, ki wọn si na owo to to owo le wọn lori nitori ọwọ to ba dilẹ nikan ni eṣu le ri bẹ lọwẹ.
Bẹẹ lo gba awọn ọlọpaa nimọran lati maa fi otitọ ṣiṣẹ, nitori ti awọn araalu le bẹrẹ si i ṣedajọ lọwọ ara wọn ti wọn ko ba nigbagbọ kikun ninu awọn ọlọpaa mọ.
Bakan naa ni kabiesi pe fun dindin agbara ijọba apapọ ku, ki wọn si ro ijọba ipinlẹ ati tipinlẹ lagbara pẹlu fifun awọn ori-ade ni ojuṣe ninu ofin orileede Naijiria, ki ẹnu wọn le to ọrọ, niwọn igba to jẹ pe awọn ni wọn sun mọ awọn araalu ju.