Faith Adebọla, Eko
Bi ọdọmọkunrin kan, Tunde Ọlaiya, ṣe maa n jade laaarọ, ti yoo wọle loru lojoojumọ naa lo ṣe mura laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, to kọja yii, ṣugbọn ko ṣee ṣe fun un lati pada waa sun sile ẹ, tori ọjọ naa lo ba awọn ikọ ọlọpaa ayara-bii-aṣa, RRS, lalejo lọfiisi wọn, latari ẹsun ole jija ti wọn fi kan an.
ALAROYE gbọ pe iṣẹ jija awọn ọlọkọ lole dukia wọn bii owo, foonu, aago atawọn nnkan ẹṣọ mi-in to lowo lori ni ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun naa yan laayo, o si ti gbowọ lẹnu iwa gbewiri ọhun.
Ki i ṣe Tunde nikan o, ọwọ tun ba ẹni keji rẹ ti wọn jọ n jale, Tokunbọ Ọmọtọla, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn.
Ọkan lara awọn ọlọpaa RRS to n fi ọkada ṣe patiroolu lo kiyesi irin kọsẹ kọsẹ ti Tunde atọrẹ n rin lagbegbe Oṣhodi-Oke ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ, niyẹn ba pe wọn lati beere ohun ti wọn n wa kiri.
Nibi tọlọpaa ọhun ti n yẹ ara wọn wo ni wọn ni Tokunbọ ti sa lọ ni tiẹ, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe Tunde, wọn si ba awọn foonu oriṣiiriṣii lapo ṣokoto ẹ ti ko le ṣalaye ẹni to ni in. Aṣe ibi ti wọn ti n lọọ ta awọn foonu ti wọn ba ja gba lọwọ ero to n rin tabi ji gbe lọwọ awọn onimọto ni wọn n lọ, kọwọ palaba wọn too segi.
Nigba ti Tunde de ọfiisi RRS, kia lo jẹwọ iru iṣẹ buruku to n ṣe ati bo ṣe n ṣe e, oun lo si ṣamọna bi wọn ṣe ri Tokunbọ to sa lọ mu lọjọ keji, toun naa fi balẹ sọfiisi awọn ọlọpaa RRS naa.
Ninu alaye ti Tokunbọ ṣe fawọn ọlọpaa, o ni latọdun 2017 loun ti n jale, ati pe ọwọ onimọto kan loun ati ọrẹ oun, Bọlaji Nigga, ti gba foonu olowo nla iPhone X ti wọn ka mọ ọn lọwọ. O ni niṣe lawọn yin onimọto naa lọrun tawọn fi ri foonu naa gba.
Awọn mejeeji ṣalaye pe ẹgbẹrun meji pere lawọn maa n ta foonu tawọn ba ji bẹẹ fun awọn to maa tun un ta l’Oshodi, tabi n’Ikẹja.
Wọn tun sọ pe awọn maa n jale lagbegbe 7-Up, Ojodu Berger; biriiji Kara, Oṣodi, titi de Mile-12, ati biriiji Ọjọta.
Yatọ si foonu, awọn nnkan mi-in ti wọn ba lapo wọn ni atike funfun kan to da bii elubọ, wọn ni nnkan oloro tajutaju tawọn maa n fẹ sawọn tawọn ba fẹẹ ja lole loju ni, ṣugbọn awọn tun maa n lo o lati fi fọ gilaasi mọto ti wọn ti ti pa.
Iwadii ti fihan pe awọn mejeeji ni wọn ti ṣẹwọn ri, bo tilẹ jẹ pe igba otọọtọ ni wọn lọ sẹwọn, afaimọ ki eyi ti wọn mu wọn fun yii ma tun da wọn pada sẹwọn ọhun.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o sọ pe iṣẹ n lọ lati mu awọn yooku ti wọn jọ n ṣiṣẹ gbewiri. Bẹẹ lo ni awọn meji tọwọ ṣi ba yii yoo fimu kata ofin nile-ẹjọ laipẹ.