Ko saaye fun iwọde ‘Oodua Nation’ nipinlẹ Ogun-Ọlọpaa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kilọ fawọn eeyan to wa nidii iwọde nitori Ilẹ Olominira Oduduwa, Oodua Nation, eyi ti wọn fẹẹ ṣe lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kin-in-ni, oṣu karun-un, ọdun 2021 yii, lati ma ṣe ohun to jọ bẹẹ rara, wọn ni ko saaye iru ẹ mọ nipinlẹ Ogun.

Alẹ Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹrin yii, ni DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, fi atẹjade kan sita, nibi to ti ṣalaye pe bawọn kan ti wọn n pariwo ‘Oduduwa Republic’ ṣe n ṣewọde kaakiri awọn ibi kan nipinlẹ yii ko tẹ ileeṣẹ ọlọpaa lọrun.

O ni ipaya ni iwọde naa n ko ba ọpọlọpọ eeyan, bẹẹ awọn to n ṣewọde yii ko yee ṣe e, wọn tilẹ tun ti n pete omi-in lọjọ Satide bayii.

Oyeyẹmi ṣalaye pe loootọ ni pe ẹtọ awọn eeyan ni lati fi ero ọkan wọn han, o ni ṣugbọn kikọja aala ti wọn mu mọ ọn, eyi to n fa ipalara fawọn eeyan mi-in ni ọlọpaa ko fẹ.

O ni lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹta, ọdun 2021 yii, awọn to n beere Ilẹ Olominira Oduduwa yii ṣe iwọde ni Iṣara Rẹmọ, nibi ti wọn ti di awọn oju ọna marosẹ pa, ti wọn si da sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ silẹ, to bẹẹ tawọn eeyan ko le rin bo ṣe wu wọn mọ latari iwọde ọhun.

Bẹẹ naa lo ni wọn tun ṣe iwọde mi-in  ni Ṣagamu lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹrin yii, to jẹ wọn tiẹ fẹẹ kọ lu wọn ni teṣan ọlọpaa Ṣagamu, beẹ awọn ọlọpaa naa ko ṣe nnkan kan fun wọn.

Bo ṣe tun di ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹrin, kan naa ni wọn tun gbe iwọde mi-in kalẹ ni Ajuwọn, nigba tawọn ọlọpaa si da wọn lẹkun pe ki wọn yee pin iwe to le da ọtẹ silẹ lọjọ naa, o ni niṣe ni wọn bẹrẹ si i juko mọ awọn ọlọpaa naa atawọn agbofinro yooku to da wọn lẹkun, bẹẹ ni wọn n fi wọn ṣe yẹyẹ.

Ẹgbẹ yii kan naa ni wọn lo tun fẹẹ ṣewọde ẹlẹẹkẹrin lọjọ Satide yii, Alukoro sọ pe iṣẹ kekere kọ lawọn ọlọpaa n ṣe lati ma ṣe jẹ kawọn ọmọọta gba iwọde naa mọ wọn lọwọ nigba ti wọn ṣe mẹta akọkọ.

O ni awọn ko ni i kawọ gbera kawọn kan maa fi ẹgbẹ wọn da wahala silẹ tabi tẹ ofin loju.

Iyẹn lo fi ni kawọn obi, alagbatọ ati ẹni gbogbo to ba fẹran alaafia, kilọ fawọn ọmọ wọn, pe wọn ko gbọdọ lọwọ si iwọde Ilẹ Olominira Oduduwa ti wọn tun fẹẹ ṣe yii, nitori kọmandi ọlọpaa ko fọwọ si i.

Wọn kilọ fawọn olori ẹgbẹ atawọn to n ṣonigbọwọ awọn iwọde naa pe ki wọn fi mọ bẹẹ, ki wọn ma jẹ ki eyi ti wọn tun n gbero ẹ yii waye rara.

Leave a Reply