Ko si ọga ileewe to gbọdọ ta aṣọ fawọn akẹkọọ l’Ọṣun- Ẹgbẹmọde

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kilọ fawọn alaṣẹ ileewe alakọọbẹrẹ ati girama lati ma ṣe ta aṣọ ileewe fun awọn akẹkọọ wọn bi wọn ṣe n mura iwọle saa eto ẹkọ tuntun yii.

Lẹyin ipade alaṣẹ to waye lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni Kọmiṣanna feto iroyin, Funkẹ Ẹgbẹmọde, sọ pe pẹlu bi awọn ileewe yoo ṣe pada si bi wọn ṣe wa tẹlẹ ko too di pe ijọba Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ko gbogbo wọn papọ, awọn akẹkọọ nilo lati ra yunifọọmu to jẹ tileewe wọn.

Ẹgbẹmọde ṣalaye pe ọdọ awọn iya alaṣọ kaakiri ọja, nipinlẹ Ọṣun, ni ki awọn obi ti lọọ maa ra aṣọ fun awọn ọmọ wọn, ko si aaye fun ọga ileewe kankan tabi awọn alaṣẹ ileewe lati ta aṣọ fun wọn.

O ni ti awọn obi ba si ti ra aṣọ ileewe tan lọja, ọdọ awọn telọ to ba wu wọn, ti wọn wa ninu ipinlẹ Ọṣun naa ni ki wọn mu un lọ, ki wọn si ran an bi wọn ṣe maa n ba awọn akẹkọọ ran an tẹlẹ.

Eredi eleyii, gẹgẹ bi Ẹgbẹmọde ṣe wi, ni lati le jẹ ki eto ọrọ-aje awọn alaṣọ atawọn telọ gberu si i nipinlẹ Ọṣun, ti yoo si tun ran awọn ẹka ọrọ-aje mi-in.

O ni ijọba ti fi anfaani ọsẹ meji silẹ fun awọn ileewe atawọn akẹkọọ lati jẹ ki ohun gbogbo wa bo ṣe wa tẹlẹ, iyẹn ni pe ki wọn bẹrẹ atunṣe to yẹ ni kete ti wọn ba ti wọle fun saa eto ẹkọ tuntun lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun yii, ki ohun gbogbo si ti gun rege ko too di ọjọ kin-in-ni, oṣu kejila, ọdun yii.

Ijọba tun rọ awọn obi ati alagbatọ lati ra gbogbo nnkan eelo ileewe awọn ọmọ wọn ninu ipinlẹ Ọṣun. Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ awọn ẹgbẹ akẹkọọ-jade nileewe kọọkan ti wọn n ran awọn akẹkọọ ileewe wọn lọwọ nipa riran aṣọ ileewe fun wọn.

Leave a Reply