Kọmiṣanna ọlọpaa Eko ṣekilọ fawọn ọba alaye: Ẹ yee ṣonigbọwọ fawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun

Faith Adebọla, Eko

 

 

 

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu, ti fi aidunnu rẹ han si bawọn ọba alaye atawọn olori ilu kan ṣe sọ ara wọn di agbodegba fawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun nipinlẹ Eko, o ni iwa to le ta epo s’aṣọ aala awọn ori ade naa ni.

Odumosu fẹdun ọkan rẹ han nibi ipade itagbangba lori eto aabo agbegbe Ikorodu fun ọdun 2021, eyi to waye ni gbọngan apero ilu naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, yii.

Odumosu ni ta a ba wo o lapapọ, eto aabo nipinlẹ Eko ti gbe pẹẹli si i, ṣugbọn ti agbegbe Ikorodu yii lo n fojoojumọ buru si i, tori laarin oṣu mẹfa pere, ojilenirugba ati meji (242) awọn afurasi adigunjale atọmọ ẹgbẹ okunkun lọwọ awọn agbofinro tẹ lagbegbe Ikorodu nikan, ibọn mejidinlọgbọn (28) ati katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin bii ọgọfa (120) ni wọn ri gba lọwọ wọn.

Awon-eeyan-to-pese-sipade-pataki-ohun.

Laarin oṣu mẹfa yii kan naa, igba o din mẹjọ (192) lawọn iṣẹlẹ idaluru latọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to waye, mejidinlogun (18) ninu awọn iṣẹlẹ yii lo la itajẹsilẹ lọ, igba mẹẹẹdọgbọn (25) si lawọn ọlọpaa tu iṣẹlẹ idigunjale fo.

Lati wa ojuutu si iṣoro yii, afi ki ijọba ibilẹ, awọn olori ilu, awọn ọba alaye atawọn baalẹ jọ fọwọsowọpọ lori ọrọ yii. O lo yẹ kawọn ori ade fi tinutinu dẹbi fun awọn ọmọ to n ṣẹgbẹ okunkun, dipo ti wọn aa fi maa ṣe koriya fun wọn, ti wọn aa maa bẹru wọn, tabi ki wọn fa wọn bọdi nigba mi-in, tabi ki wọn maa fi oye da wọn lọla.

Odumosu-atawon-oba-nipade-naa

“Awọn oniṣẹṣe atawọn oloogun ibilẹ gbọdọ jawọ ninu ṣiṣe oogun abẹnugọngọ fawọn ẹlẹgbẹ okunkun, akoba nla ni aṣa naa n mu wa fun iṣẹ aabo ilu tawọn ọlọpaa n ṣe. Ọpọ igba lawọn ẹlẹgbẹ okunkun atawọn afurasi adigunjale n gboju le oriṣiiriṣii oogun abẹnugọngọ bii igbadi, ifunpa, onde, tira ti wọn so kọra lati ṣiṣẹ ibi wọn.

“Ẹyin lanlọọdu ati lanledi, o yẹ kẹ ẹ ṣewadii gidi tawọn ọmọkọmọ wọnyi ba fẹẹ gba ile lọwọ yin. Ko yẹ kẹ ẹ da gbogbo ẹ da kiateka nikan. To ba si jẹ lẹyin ti wọn ti gba ile tan lẹ too fura, ki lo de tẹ o ki i jẹ kawọn agbofinro gbọ, ka si ran yin lọwọ nitori ibẹru?

Ni ti awọn aṣaaju ẹsin, dipo ki iwaasu wọn da lori bawọn eeyan ṣe gbọdọ di olowo ati ọlọrọ, niṣe lo yẹ ki wọn kọ wọn lati jẹ eeyan alaafia, ki wọn si maa ṣi wọn leti nipa ibaṣepọ ati igbesi aye alaafia ati aabo.”

Odumosu ni ko sẹni to mọ awọn agbegbe naa to awọn ọba alaye atawọn baalẹ adugbo, ati pe bi ina ko ba ni awo, ko le jo goke odo, bii owe Yoruba ṣe sọ.

Lara awọn eeyan pataki to wa nikalẹ lọjọ naa ni Ayangburẹn tilu Ikorodu, Ọba Kabiru Shotobi, Adeboruwa ti ilu Igbogbo, Ọba Sẹmiudeen Kasali, Alaga ijọba ibilẹ Ikorodu, Ọnarebu Wasiu Adeṣina, atawọn ọba alaye mi-in.

Leave a Reply