Kọntena run ọkọ ayọkẹlẹ meji womuwomu lori biriiji Ọtẹdọla, ẹni kan ku, ọpọ fara pa

Faith Adebọla, Eko

Ẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun ni eeyan mẹta, titi kan dẹrẹba to wa ọkọ ajagbe to pọn kọntena sẹyin kan ṣi wa bayii lọsibitu ti wọn gbe wọn lọ, latari bi kọntena naa ṣe ja bọ lu awọn ọkọ ayọkẹlẹ meji kan lori biiriji Ọtẹdọla, nipinlẹ Eko, lọjọ Aiku, Sannde yii, to si ṣeku pa ẹni kan loju-ẹsẹ.

Iṣẹlẹ yii la gbọ po waye lọsan-an ọjọ naa, wọn ni ibi tawọn ọkọ ti n pẹwọ fun awọn kọnkere ti awọn to n tun apa kan biriiji naa ṣe ko saarin titi ọhun ni kọntena to wa lẹyin ọkọ ajagbe kan ti re bọ lojiji, to si run awọn ọkọ ayọkẹlẹ meji to wa lẹgbẹẹ rẹ womuwomu. Nọmba awọn ọkọ ayọkẹlẹ naa ni Lagos JJJ 28 FR ati Lagos BDG 597 CY.

Ọgbẹni Nosa Okunbor, Alukoro fun ileeṣẹ to n ri si ọrọ pajawiri nipinlẹ Eko, Lagos State Emergency Management Agency (LASEMA), sọ nipa iṣẹlẹ ọhun ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Sannde pe awakọ tirela to gbe kọntena naa fara pa gidi, ibi ti wọn si ti n gba itọju pajawiri lawọn gbe e lọ, pẹlu awọn meji mi-in ti wọn fa yọ ninu awoku ọkọ ayọkẹlẹ naa, o ni wọn wa ni ọsibitu Trauma Centre, to wa lẹgbẹẹ ileeṣẹ awọn ẹsọ alaabo oju popo (FRSC) nitosi Too-geeti ọna Eko s’Ibadan.

O ni o ṣe ni laaanu pe ọkan ninu awọn dẹrẹba ọkọ ayọkẹlẹ naa ku loju-ẹṣẹ, o ni Ọgbẹni Lawal ni wọn porukọ ẹ, awọn mọlẹbi ẹ si ti yọju lati gba oku ẹ, ki wọn le lọọ sin in.

Bakan naa lo ni awọn oṣiṣẹ ajọ LASEMA ti wọ awọn awoku ọkọ ọhun ati kọntena to gun lẹsẹ bata ogoji to ja bọ naa kuro laarin titi, ki wọn ma baa ṣediwọ fun lilọ bibọ ọkọ.

O lo anfaani naa lati parọwa fawọn onimọto lati maa fẹsọ ṣe loju popo, paapaa lasiko pọpọṣinṣin ọdun Ileya to wọle yii.

Leave a Reply