Kootu gbẹsẹ le apo ikowosi ati ile Bidemi Rufai, ọmọọṣẹ Dapọ Abiọdun tẹlẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Eko ti gbẹsẹ le apo ikowosi Abidemi Ganiu Rufai, ọmọọṣẹ Gomina Dapọ Abiọdun tẹlẹ to n ṣẹwọn l’Amẹrika, lori ẹsun jibiti ori ayelujara. Bakan naa ni wọn si tun gbẹsẹ le ile rẹ to wa ni Lẹkki, nipinlẹ Eko.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹjọ, nile-ẹjọ paṣẹ yii, bo tilẹ jẹ pe fun asiko kan naa ni gbigbẹsẹ le yii yoo jẹ, ẹsẹkẹse lo ti di aṣẹ.

Adajọ Tijani Ringim lo paṣẹ yii, awọn akanti Rufai to fofin de naa jẹ ti banki Sterling ati Zenith. Ile ọkunrin naa to wa l’Ojule kọkanla, Opopona Ọmọdayọ Awotuga, Bera Estate, Chevy View, ni Lekki, nipinlẹ Eko, ni kootu gbẹsẹ le.

Lọọya kan to n ṣoju EFCC, Ebuka Okongwu, lo kọwe si kootu, pe o ṣe pataki lati fofin de awọn apo ikowo si Bidemi Rufai, lati fopin si bi owo ṣe n jade nibẹ ninaakunaa, iyẹn awọn owo to mu ifuradani to n wọ awọn asunwọn naa.

Iwadii ti EFCC ṣe lori inaakunaa owo ninu akanti yii, fidi ẹ mulẹ pe Rufai ti gba owo kan to din diẹ ni ọgbọn miliọnu naira (29.37m). Wọn ni niṣe lo pin owo naa yẹlẹyẹlẹ, to gba a ni miliọnu marun-un, meji, miliọnu kan aabọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Koda, niṣẹ ni ajọ EFCC da Rufai, ileeṣẹ rẹ, Omo Mayodele Global Investment, ati Banki Sterling pọ gẹgẹ bii olujẹjọ lori ẹsun yii.

Adajọ Ringim loun gba abọ iwadii EFCC yii wọle, oun gbe ote le akanti olujẹjọ yii ati ile rẹ to wa ni Lekki. O ni ki EFCC fi atẹjade sita lori igbesẹ ile-ẹjọ yii, laarin asiko yii si ọsẹ meji, ki ẹnikẹni to ba ni idi kan ti kootu ko fi gbọdọ gbẹsẹ le asuwọn ati ile naa le waa sọ tẹnu wọn.

O sun igbẹjọ si ọjọ kin-in-ni, oṣu kejila, ọdun 2021.

Tẹ o ba gbagbe, ikọ oniwadii FBI lo mu afurasi yii lọjọ kẹrinla, oṣu karun-un, ọdun yii, ni papakọ ofurufu John.F.Kennedy to ti fẹẹ wọ pileeni, ni New York.

Ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ataabọ dọla, ($350,000) owo iranwọ ti wọn fẹẹ san fawọn ti ko niṣẹ lasiko Korona, ni Washinton, ni wọn ni Bidemi fi ọgbọn yahoo wọ jade lapo awọn oyinbo, to da a sapo tiẹ, to n ṣe faaji kiri.

Atigba ti wọn ti mu un naa lo ti wa lahaamọ lọhun-un, wọn ko gba oniduuro rẹ, nitori wọn ni ẹṣẹ to ṣẹ kọja owo yii, awọn jibiti to nipọn buruku lo ti lu lawọn ilu mi-in niluu oyinbo, o si gbọdọ duro ko gba idajọ ẹ labẹ ofin ilẹ awọn ni.

Ọrọ yii lo yọ afurasi naa niṣẹ nipinlẹ Ogun to ti gbapo olubadamọran fun Gomina Abiọdun, ijọba Ogun yọ ọ nipo, wọn lawọn ko lọwọ si ọrọ jibiti to sọ Bidemi deroo gbaga.

Leave a Reply