Faith Adebọla, Eko
Awuyewuye to n ja ranyin laarin ẹgbẹ awọn onimọto ati igbimọ tijọba Eko gbe kalẹ lati maa ṣakoso awọn onimọto l’Ekoo, eyi ti wọn yan Alaaji Musiliu Akinsanya tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ gẹgẹ bii alaga rẹ, ti gbọna mi-in yọ bayii. Ile-ẹjọ ti paṣẹ pe wọn o gbọdọ gba owo tikẹẹti kan lọwọ awọn onimọto mọ, wọn o si gbọdọ dunkooko mọ ẹnikẹni.
Adajọ Peter Lifu ti ile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ sagbegbe Ikoyi, l’Erekuṣu Eko, lo paṣẹ naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Aṣẹ naa waye latari ẹjọ kan ti Ọgbẹni Olukọya Ogungbejẹ pe, gẹgẹ bii agbẹjọro fun ẹgbẹ onimọto tuntun kan ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ, Transport Union Society of Nigeria (TUSN).
Olupẹjọ naa rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ pe ki eyikeyii lara awọn olujẹjọ ma ṣe yọ awọn onimọto ti ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ wọn lẹnu titi ti wọn yoo fi gbọ koko ẹjọ ti wọn tori ẹ wa si kootu naa.
O ni wọn o gbọdọ jawee, ja tikẹẹti, beere owo, ibaa jẹ owo ẹgbẹ, owo gareeji, lọwọ awakọ ero kankan, wọn o si gbọdọ fiya jẹ onitọhun tabi ki wọn ni ki ẹni naa waa rojọ kankan.
Awọn ti wọn to orukọ wọn sinu iwe ipẹjọ naa gẹgẹ bii olujẹjọ ni ẹgbẹ onimọto NURTW (National Union of Road Transport Workers), RTEAN (Road Transport Employees Association of Nigeria), NARTO (Nigerian Association of Road Transport Owners), Alaaji Lawal Othman, ijọba ipinlẹ Eko, kọmiṣanna feto idajọ l’Ekoo, ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, ati ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, DSS (Department of Security Service).
Gbogbo ẹbẹ yii ni adajọ fontẹ lu.
Amọ ṣa, adajọ naa paṣẹ pe kawọn olujẹjọ wọnyi waa ṣalaye ara wọn, ki wọn si jẹ kile-ẹjọ mọ ero wọn lori ẹbẹ ti olujẹjọ naa bẹbẹ fun, ati lori awọn ẹjọ mi-in to wa nilẹ laarin ọsẹ kan pere, ki idajọ too waye.