FAITH ADEBỌLA
Bi ọrọ ba ti jẹ mọ ọrọ aabo nibikibi, ọrukọ ileeṣẹ ọlọpaa ko le gbẹyin nibẹ. Ẹni to rinu rode nileeṣẹ naa lori eto aabo. Alukoro apapọ funleeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa, Ọmọọba Olumuyiwa Adejọbi, gba ikọ ileeṣẹ ALAROYE lalejo laipẹ yii, a si sọrọ lẹkun-unrẹrẹ lori idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ, awọn ọlọpaa ti wọn n yan tẹle awọn ọlọla lawujọ, ati ọna abayọ to wa fun eto aabo. Akagbadun ni!
ALAROYE: Ọpọ iṣẹ oriṣiiriṣii lo wa teeyan le yan lasiko tẹ ẹ wọṣẹ ọlọpaa, ki lo fa a to fi jẹ iṣẹ yii lẹ yan laayo?
Ọmọọba Adejọbi: Baba to bi mi, olukọ ni, tiṣa ni, ko too di ọba niluu Orile-Owu, nipinlẹ Ọṣun. Iya to bi mi lọmọ, olukọ ni, ko too di olori, ayaba laafin. Baba mi lo pinnu pe awọn ọmọ oun gbọdọ wa ni ilana, yala olukọni, tabi agbofinro, tabi apẹtu-saawọ lawujọ. Ṣugbọn o da bii pe wọn yan iṣẹ ọlọpaa laayo, wọn o ṣiṣẹ ọlọpaa ri o, ṣugbọn wọn nifẹẹ si iṣẹ naa pupọ. Ni idile wa, ni ila baba mi Oladoṣu Adejọbi, awa mẹrin la jẹ ọga ọlọpaa latibẹ, akọbi ẹ lọkunrin, Igbakeji kọmiṣana ọlọpaa ni (Assistant Commissioner of Police) ni, emi naa ati iyawo mi, ọga ọlọpaa ni wa, ẹgbọn ti mo tẹle, ati iyawo wọn, ọga ọlọpaa lawọn mejeeji. Ṣugbọn ni idile Adejọbi lapapọ, awa ta a jẹ ọlọpaa n lọ si bii ogun. Nibi ta a si pẹka de, a fẹrẹ to aadọta lẹnu iṣẹ ọlọpaa. Baba wa fẹran iṣẹ ọlọpaa pupọ, oun lo fi n tẹ ẹ mọ wa leti pe ka ṣiṣẹ naa. Eyi ti ko si ṣe ọlọpaa ninu wa, olukọni agba lo jẹ ni fasiti. Eyi ti o si ṣe ọlọpaa tabi olukọ laarin wa, iṣẹ to tan mọ ṣiṣamojuto awọn eeyan loun naa n ṣe, iyẹn Abilekọ Iyabọ Ogunyẹmi, Head of Local Government Administration, l’Ejigbo, l’Ekoo. Ba a ṣe tan lẹka ẹka niyẹn, ṣugbọn iṣẹ ọlọpaa lo laami-laaka ju laarin idile wa.
Emi gẹgẹ bii ẹni kan, mo ti wa lẹnu iṣẹ yii, o ti pẹ diẹ. Mo dara pọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ọdun 2005, iyẹn ọdun mejidinlogun sẹyin. Gbogbo asiko ti mo si lo lẹnu iṣẹ yii, eyi to pọ ju ninu ẹ ni mo fi siṣẹ alukoro tabi akọwe. Mi o nifẹẹ siṣẹ to le mu kawọn eeyan ro pe boya owo la n wa, tabi ka maa fẹgẹ, ka maa ko girigiri b’awọn eeyan, mi o nifẹẹ si i. Mo fẹran iṣẹ alukoro pupọ, mo si nifẹẹ si pipẹtu saawọ. Tori ki n too darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa, mo ti kawe-gboye akọkọ ninu ẹkọ nipa iwakusa-aṣa, ti wọn n pe ni archeology, lati Fasiti Ibadan (University of Ibadan), mo si tun kẹkọọ-gboye ni ipele masitaas (Masters) ninu imọ nipa alafia ati ipẹtu-saawọ (Peace and Conflict Studies). Imọ ti mo ni wọnyi ni mo da pọ mọ ẹkọ ti mo kọ lẹnu iṣẹ ọlọpaa, eyi ti gbogbo ẹ da lori ipẹtu-saawọ, ibagbepọ ẹda, ajọṣe laarin ojugba, wiwa alaafia ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Mo dupẹ ibi ti mo ba a de yii o. O wu mi lọkan ki gbogbo araalu nifẹẹ iṣẹ ọlọpaa, ṣugbọn fun idi kan tabi omi-in, ko ri bẹẹ.
ALAROYE: Ẹ ni ọlọpaa ni yin, ọlọpaa naa si niyawo yin, bawo lẹ ṣe n ṣe ojuṣe yin nile?
Ọmọọba Adejọbi: (o rẹrin-in musẹ) Bo ti mọ ni yoo mọ o, ọkọọyawo yoo lọdii. Aaye n wa, o kan le ma jẹ lojoojumọ ni. Iwọnba aaye to ba yọju naa, eyikeyii oore-ọfẹ to ba ti wa, a n lọ sile, a si n ṣe ojuṣe. Ibadan lawọn idile mi wa, irin-ajo Abuja si Ibadan fẹrẹ ma ju aadọta iṣẹju lọ, owo ni yoo kan na eeyan ni (lati gun baaluu). Igba mi-in ẹwẹ, awọn naa n yọju si wa lọfiisi. Koda nigba toju ogun le, ti ipo mi ṣi kere si eyi ti mo wa yii, ta a ṣi wa ni sisare soke sodo bii ologinni iya agba, a kuku n ri aaye. O jẹ ki n ranti ọga mi kan ni, nigba ti mo bimọ ti mo lọọ yayọ fun wọn, wọn lanu pe bawo ni mo ṣe ṣe e, pẹlu gbogbo airaaye yii. Mo ni ‘ọga, eyi ta a fi n ṣere ọmọ ko ju iṣẹju marun-un naa lọ’, ṣoki ladiẹ n ṣere ifẹ, ninu airaaye yii naa la gbọdọ dọgbọn si i. Iyawo mi wa pẹlu awọn ọmọ, a si n kọ wọn lẹkọọ to yẹ, iṣẹ ọlọpaa naa faaye gba kawọn obi to jẹ ọlọpaa wa larọọwọto awọn ọmọ wọn, ki wọn le kọ wọn bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ ni ilana ofin, ilana ẹkọ, ati ilana aṣa. Emi o ro pe a gbọdọ ri ọmọ kan ninu ọmọ iru awa yii, ti ko ni i mọ nipa aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba, tori ọpọlọpọ awọn iwa buruku to gbode kan lawujọ wa yii, tori pe a ti sọ aṣa ati iṣe Yoruba nu lo n ko ba wa. Ko si ọmọ mi kan to le dide pe oun fẹẹ lọ kẹgbẹkẹgbẹ, ma a bi i leere pe ta lo fẹẹ fi iyẹn jọ? Emi gbagbọ pe ta a ba mu aṣa ati iṣe wa lọkun-un-kun-un-dun, awọn ipenija wa yii ko ni i pọ.
ALAROYE: Ọrọ aabo tubọ n buru si i ju tatẹyinwa lọ ni lorileede yii, loju tiyin, ta lo jẹbi eto aabo to n fojoojumọ bajẹ yii?
Ọmọọba Adejọbi: Ninu ere aye atijọ kan, ‘Ṣaworo Idẹ’, Baba Ọpalamba kọrin kan nibẹ, wọn ni: “Ọrọ lẹyẹ n gbọ, ẹyẹ o deede ba lorule o, ọrọ lẹyẹ n gbọ o.” Ẹni ba beere ọrọ lo n fẹ idi ẹ gbọ. Mo ti sọ lede eebo ninu awọn ifọrọwanilẹnuwo ti mo ṣe kan pe emi gẹgẹ bii ẹni kan, mi o nigbagbọ pe eto aabo orileede yii mẹhẹ to bẹẹ. Ọpọlọpọ wa, a ki i ṣọmọluabi lorileede Naijiria, a o nigbagbọ ninu orileede yii mọ, eyi tawọn eleebo n pe ni patriotism, koda a o nifẹẹ orileede wa bo ṣe yẹ mọ.
Fun apẹẹrẹ, awọn ti wọn n ja lapa Oke-Ọya, ti wọn n pa ara wọn, wọn ki i ṣe ajeji, ọmọ orileede yii ma ni wọn. Awọn ti wọn n pa ara wọn, ti wọn n pe ni IPOB, wọn o ki i ṣe ara-ita, ọmọ orileede yii naa ni wọn, ede kan naa ni wọn n sọ, awọ kan naa ni wọn si ni. Awa ara wa la n pa ara wa. Iyẹn ki i ṣe ipenija eto aabo. Emi Adejọbi, iwọ Adejọbi, oun Adejọba, a waa jẹ meje, a pe ara wa jọ, a n ṣepade, ẹni kan waa dide laarin wa, o fa ibọn yọ, o pa awọn mọlẹbi ẹ, ṣe eto aabo lo mẹhẹ yẹn ni? Eto aabo kọ niyẹn, Eṣu to n gbe inu ẹ ni kẹ ẹ jẹ ka beere, eedi wo lo di i to fi n ṣe awọn eeyan ẹ ni ṣuta.
Gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria patapata, ko ju nnkan ti mo sọ yii lọ. Awọn agbẹ ti wọn wa ninu oko wọn lapa Oke-Ọya, ti awọn kan si faṣọ dudu boju, ti wọn yọ si wọn, ti wọn si pa wọn sibẹ, ede kan naa ni wọn n sọ, ọmọọya kan naa ni wọn. Ki lo mu keeyan maa pa elede ẹ, ṣe arun ọpọlọ ni, abi awọn nnkan ta a gba gbọ lọwọlọwọ bayii, ti wọn n pe ni ideologies lo n ko ba wa. Awọn kan gbagbọ pe ti wọn ba pa gbogbo eeyan, awọn aa ri ijọba ọrun wọ, iru igbagbọ bẹẹ ki i ṣe igbagbọ wa. Awọn kan lawọn n ba ijọba ja, awọn fẹẹ ya kuro ni Naijiria, wọn fẹẹ da duro, wọn fẹẹ gba ijọba tiwọn, la wa n pa ara wa, beeyan ba pa gbogbo araalu tan tori ati jọba, ta ni tọhun fẹẹ jọba le lori.
Iyẹn lo fi jẹ pe awa la n fọwọ ara wa ṣe ara wa. O si ti to akoko to yẹ ka pe aro ati ọdọfin inu wa, ta a o pe ọtun atosi, lati jiroro bawo la ṣe fẹẹ yanju ọrọ to wa nilẹ yii. Ailaṣọ lọrun paaka, o to nnkan apero fọmọ eriwo. Eto aabo wa o mẹhẹ, awa la n pa ara wa, awa la n ṣe ara wa leṣe, awa la n fun ara wa ni majele jẹ, awa la n ji ara wa gbe, ko si ara Oke-Ọya nibẹ, ko si oyinbo kankan nibẹ, ọmọ Naijiria yii naa ni gbogbo wa, awa la n gba abọde fun ara wa, fun idi kan tabi omi-in, ọpọlọ ni ta a ba debi iru, ka fo o.
Ṣugbọn ka ma gbagbe o, ẹni to tori adun ọgẹdẹ, to fi gbogbo ile pọn ọti agadagidi, o ti gbagbe pe ti ọgẹdẹ ba pawada tan, niṣe ni i pa ni ju ọti lọ. Ka ro o daadaa, ta a ba ni a n binu, a n ba orileede Naijiria jẹ, nibo la fẹẹ sa lọ, ko si orileede adulawọ tabi ti ilẹ oyinbo to ṣetan lati gba gbogbo wa silẹ wọn. Bẹnikan ba ro pe ti ilu yii ba daru pẹnrẹn, oun aa di ẹru oun, oun aa sa lọ, irọ ni o, awọn to lero pe wọn maa gba oun sile yẹn, wọn maa tilẹkun wọn ni. Tori ẹ, ka ronu ara wa wo ni.
ALAROYE: Lẹnu lọọlọọ yii, lemọlemọ lawọn ọlọpaa n padanu ẹmi wọn, bẹẹ ko ri bẹẹ nigba kan, ẹ si leto aabo ko mẹhẹ?
Ọmọọba Adejọbi: Nilẹ Yoruba, wọn ni a ki i ra kun ogun ologun pin, ohun t’ologun ba fi silẹ naa la o ba a pin. O si jẹ mọ nnkan ti mo sọ laipẹ yii. Awọn kan ti lero pe ijọba apapọ lawọn n ba ja, gbogbo agbefọba tawọn ba ti ri lawọn yoo si maa pa. Wọn mu un ni ibaada ni, wọn mu ni iṣẹ ni, pe tawọn ba ti jade lojumọ kan, awọn gbọdọ ta ẹjẹ ọlọpaa silẹ ni, Ọlọrun ni ko gba fun wọn. Agbara ojo ko loun o ni ile i wo, onile ni o ni i gba fun un.
Ki i ṣe ọlọpaa nikan, awọn ṣọja ti wọn jẹ ologun gan-an, ti wọn ni nnkan ogun ju wa lọ, awọn naa n fara gba ninu ẹ, awọn onṣejọba, awọn alaṣẹ naa n ba a lọ, ko si ẹka ti ko de. Tẹ ẹ ba wo o, titi de ṣọọṣi, de mọṣalaaṣi wọn n fara kaaṣa, ki i ṣe ọlọpaa nikan. Idi ẹ ko si ju pe awọn agbesunmọmi, awọn eeṣin-o-kọ’ku ti wọn lawọn n ba ijọba ja, wọn o kọ kilẹ ṣu lọsan-an gangan. Awọn ọmọ ijọba, awọn agbofinro, ni wọn si n pa, ki wọn baa le fiya jẹ ijọba, ko baa le dun ijọba, ko le ka ijọba lara, irọ si ni wọn n pa. Tori ẹ lawa naa o ṣe ni i beṣu bẹgba, a o jọ koju ara wa ni o. Oni o jọ tanaa, igbago kanra gogo. Ẹ o ri i pe lẹnu ọjọ mẹta yii, pipa ti wọn n pa awọn ọlọpaa dinku diẹ, tori awọn nnkan ija nla kan wọle fawa naa, ta a fi n dana ya wọn. Agba-wọle ni teerin, akan-wọlẹ ni teekan, ti wọn ba lawọn o ni i gba, awa naa o ni i gba.
ALAROYE: Lati ro eto aabo lagbara, njẹ ẹ fara mọ idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ?
Ọmọọba Adejọbi: Ko sohun to buru nibẹ, ko buru rara. Bi ẹran ba sopa, idunnu ọlọdẹ ni. Ṣugbọn ọrọ ofin ni, ọrọ ofin orileede wa ni, ti wọn o ba ṣatunṣe si ofin, o ṣee ṣe ki idasilẹ ọlọpaa ibilẹ tabi ti ipinlẹ ma ṣee ṣe. Iṣẹ si n lọ lori ofin naa, nigba ta a ba de ori afara, a o mọ ọna lati sọda ẹ. A ni lati ṣatunṣe lori ofin to ko wa ni papa mọra lori ọrọ ọlọpaa ipinlẹ lọwọlọwọ, ko si si nnkan tawa naa le sọ lori ẹ. Ti atunṣe bẹẹ ba wa, ti wọn si da ọlọpaa ipinlẹ silẹ, ọhun to daa ni. A ki i ri ẹni ran ni lẹru, ka ru aruyọke o. Ọlọpaa ni baba-baba gbogbo ẹka agbofinro jake-jado orileede yii, latọdun 1862 la ti n ba a bọ. Ko si ẹka ileeṣẹ agbofinro ti ki i ṣe ara ọlọpaa ni wọn ti ya, bo si ṣe ri kaakiri awọn orileede agbaye niyẹn.
Awa naa gbọdọ ro awọn ọlọpaa lagbara bo ṣe yẹ. Ti a ba ro wọn lagbara, awọn kudiẹ-kudiẹ to n yọ silẹ yii yoo di nnkan afisẹyin teegun n fi’ṣọ.
ALAROYE: Awọn kan mu aba wa pe nibi tọrọ de yii, kijọba kuku gba gbogbo araalu laaye lati maa gbebọn, ki lẹ ri si i?
Ọmọọba Adejọbi: Ta a ba ni ki were ṣe oku iya rẹ bo ṣe wu u, yoo sun oku iya rẹ jẹ o. Awọn baba wa si sọ pe aworo to ya lugbin, tori ijo layẹwu, ọrọ ẹ gba suuru o. Ẹni ti o ba loju inu, tita ẹ n pọn yan lakọsẹ ni. A o ti i to, a o dagba to, a o loore-ọfẹ to ki kaluku maa gbebọn lorileede Naijiria o, emi o fọwọ si i, gbogbo awọn to si laṣẹ naa ti lawọn o fọwọ si i, wọn ni ko ti i ri bẹẹ. Ko ti i to, ko ti i yẹ, lati jẹ kawọn eeyan maa gbebọn bẹẹ. Ohun to yẹ ka ṣe ni riro awọn ẹka agbofinro wa lagbara, lati ṣe ohun to tọ, ateyi to yẹ. Ba a ba ni ki gbogbo wa gbebọn, hun-un, awọn orileede ti wọn ṣeru ofin bẹẹ gan-an, wọn ti n geka abamọ jẹ. A le wa lagboole ka la n ṣe ikomọ, ẹnikan aa si ṣadeede yọ si wa, aa paayan bii ogun bii ọgbọn, ṣe iyẹn mu ori pipe wa. O ti o, o ku-diẹ-ka-a-to. Ẹ jẹ ka ṣe e pẹlẹpẹlẹ, ko ti i to asiko lati ṣeru ẹ, afi ta a ba fẹẹ feṣu ṣe ara wa lo ku o.
ALAROYE: Awọn ipenija wo lẹ ti ba pade nidii iṣẹ alukoro ọlọpaa, bawo lẹ si ṣe koju wọn?
Ọmọọba Adejọbi: Wọn kọ ọ nile ọgbọn, wọn wo ẹ nile imọ, ọgbọn leeyan o ni i gbọn ni, abi imọ ni tọhun o ni i mọ. Ko si nnkan to wa ninu iwa tẹmbẹlẹkun, iwa ọtẹ, gbigbesunmọmi, ahesọ, isọkusọ, ti ko ba mi lara mu. Mo sọ lẹẹkan pe baba to bi mi, ọba alade ni. Ko si nnkan ti ko ba awa lara mu. A le sọrọ pe kawọn eeyan ṣe bayii, ta a ba fẹẹ sọ ọ jade, awa naa maa kọkọ ronu ibi tawọn eeyan le gbe ọrọ wa yẹn gba, iyẹn lo maa jẹ ka mọ ohun ta a fẹẹ sọ ati ba a ṣe maa sọ ọ.
Ṣugbọn niluu ta a wa yii, tori pe ọpọlọpọ eeyan o nifẹẹ si iṣẹ ọlọpaa, to o ba ba wọn soootọ ọrọ, niṣe ni wọn maa yi i si nnkan mi-in. Igba mi-in si ree, niṣe ni wọn maa n ṣaaju ẹlẹẹẹdẹ pe ẹẹdẹ, mo le fẹẹ sọ pe ẹẹdẹgbẹfa, awọn aa ti ba mi sọ ọ di ẹẹdẹgbẹsan-an tabi ẹẹdẹgbeje, ti ko si ri bẹẹ. Iwa tẹmbẹlẹkun ati ahesọ ọrọ lo jẹ ipenija to pọ ju, ṣugbọn nitori awa naa ti mọ bẹẹ, wọn lẹni to maa ba Esu jẹun, ṣibi ẹ gbọdọ gun. Awa naa ti mura tiwọn mọ ọn.
Ju gbogbo ẹ lọ ni pe awọn ipenija wọnyẹn ti mọ wa lara o, ko jọ awa loju, tori oniluu ko ni i fẹ ko tu. Awa lawa niluu, tori ẹ, a o ni i kọdi sita ka tọ sinu ile, a o ni i fẹ ki orileede Naijiria bajẹ.
Wọn tun maa bẹrẹ omi-in bayii, ṣebi a ti bẹrẹ ipolongo ibo, awa naa si ti mura pe ba o tiẹ sọ, wọn aa ni a sọ, ba o wi, wọn aa la a wi. Fun apẹẹrẹ, lori ẹrọ ayelujara lanaa (ọjọ Sannde, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹwaa yii) ni wọn gbe e pe awọn kan n ja, wọn n ṣe iwọde, wọn ko ibọn sọwọ kitikiti, ẹnikan lo gbe e jade pe o ṣẹlẹ lanaa. O ni kawọn eeyan wo o, awọn kan ni wọn ṣewọde yii o, ki lawọn ọlọpaa n wo, ko sọlọpaa to di wọn lọwọ o, ṣugbọn nigba tawọn fẹẹ ṣe iwọde tawọn, awọn ọlọpaa o gba o. Mo waa n bi i leere pe ṣe ana ni eleyii waye abi 2015? Ọdun meje sẹyin ni fọto to gbe si i yẹn, teeyan ko ba ni suuru, ti o fara balẹ wo fọto yẹn, ti o mọ itan to bi i, tọhun aa ro pe loootọ lawọn ọlọpaa ko ṣe nnkan to yẹ ki wọn ṣe, bẹẹ irọ ni.
Ṣugbọn ni tiwa, a ti mọ awujọ ta a wa, eeyan ki i nigi lọgba koma mọ eeso ẹ, a mọ iwa awọn eeyan wa lorileede yii.
ALAROYE: Ipa wo ni yiyan ọlọpaa lati maa tẹle awọn eeyan nla lawujọ ni lori ileeṣẹ yin?
Ọmọọba Adejọbi: Nnkan ti ofin ba ni ka ṣe, a gbọdọ ṣe e, awọn kan wa to jẹ pe labẹ ofin, wọn lẹtọọ si pe ka yan ọlọpaa tẹle wọn, a gbọdọ fun wọn ni ẹṣọ to maa maa duro lẹyin wọn, eyi tawọn eleebo n pe ni (ADC), ẹtọ wọn labẹ ofin ni, a ni ọlọpaa to o, a ko ni to o, a gbọdọ wa a ni, tulaasi lobinrin n wa nnkan ọbẹ.
Ekeji ni pe awọn kan jẹ ogunna-gbongbo niluu, ọtọkulu ilu ti ofin ni a gbọdọ wo sakaani wọn, lati mọ boya njẹ ẹmi wọn o ni i wa ninu ewu ta o ba fi ọlọpaa ti wọn. Fun apẹẹrẹ, ẹ wo awọn eeyan nla nla ti wọn wa nidii eto okoowo wa ni Naijiria, ti awa naa si mọ peeyan nla ni wọn, tọ ba n rin lọ ni titi, ti ko si ọlọpaa lẹyin wọn, awọn araalu gan-an aa bu wa, awọn kan wa ta a mọ bẹẹ, ti a si gbọdọ ṣeto ẹ fun.
Awọn kan wa ti wọn jẹ ọba alaye, ti wọn jẹ ọba gidi, wọn lẹtọọ lati fi ọlọpaa ṣọla, yatọ si ti pe ki wọn daabo bo wọn, wọn gbọdọ fẹla, awọn ọba nla nla, awọn ori alade kaakiri gbogbo Naijiria, ẹmia ni o, ọba ni o, eze tabi igwe ni o, awọn ọba onipo ki-in-ni, a gbọdọ fun wọn ni ọlọpaa.
Ṣugbọn awọn kan wa ti ko lẹtọọ si i, to jẹ pe wọn niṣe ni wọn fi mimu ọlọpaa kiri dọrẹẹ, bii pe ‘ọrẹ mi mu ọlọpaa kiri, emi naa fẹẹ lo ọlọpaa,’ awọn naa fẹẹ gba ọlọpaa, igba kan wa ti wọn fẹẹ maa fowo ṣe e, la ṣe kilọ pe ta a ba ni ka fi towo ṣe e, niṣe ni yoo ba gbogbo ẹ jẹ, ẹ jẹ ka maa ṣe e diẹdiẹ.
Awa naa waa ri awọn alafo to n pa ileeṣẹ wa lara, ta a ba fun eeyan kan ni ọlọpaa mẹrin, bi ọrẹ ẹ ba n lọ ode, yoo waa ya a ni meji lara wọn, leyii ti ko si boju mu, ko yẹ ko o ya ọrẹ ẹ ni ọlọpaa. Ti ọrẹ ẹ ba fẹẹ gba ọlọpaa, ko kọwe si wa, to ba tọ si i, a maa fun un. Ki wọn si ri i pe awọn ọmọ ta a yan tẹle wọn, wọn o fiya jẹ wọn.
Ṣugbọn emi n sọ ọ, ti wọn ba yan mi tẹle eeyan to ba n fiya jẹ mi, ma a fẹjọ sun awọn ọga mi nibiiṣẹ mi pe mi o ṣe mọ, ẹni tẹ ẹ yan mi sọdọ ẹ n fiya jẹ mi.
Arabinrin to lu ọlọpaa ti wọn yan fun un, to fọ ọ lẹnu, ti ẹnu ẹ bẹjẹ, Purofẹsọ kan ni o, nnkan ti ọmọ yẹn sọ ni pe o fiya jẹ oun, iṣẹ to ni koun ṣe ki i iṣẹ oun, iyẹn lo dija. Mo si mọ pe awọn ọlọpaa naa ti kẹkọọ lara iṣẹlẹ yẹn, wọn lẹtọọ lati sọ pe ẹni tẹ ẹ yan mi ti yii o, iṣẹ palapala, iṣẹ ti ko bojumu lo n lo mi fun, aa si yọ irufẹ ọlọpaa bẹẹ kuro nibẹ. Ẹlomi-in wa ninu wọn to buru debii pe loootọ labẹ ofin, o yẹ ka fun un lọlọpaa, ṣugbọn tori to n fiya jẹ awọn ọmọ wa, ko ni i fun wọn lounjẹ, ti ara omi-in ko ba ya ninu wọn, aa ni ‘ṣebi oun n sanwo loṣu,’ ọtọ ni ka sanwo oṣu fun awọn oṣiṣẹ wa, ọtọ ni ka mu inu wọn dun. Eleto aabo to n tẹle iwọ kiri, to o ba tọju wọn, ọwọ ọta yoo ba ọ, ibi to yẹ ko ti gbeja ẹ, ti ko ba gbeja ẹ, bii ọrọ aja ni, ẹni ti ko ba tọju aja ẹ, aja naa ko ni i gbeja ẹ.
ALAROYE: Ṣe bo ba wu eeyan to lowo lọwọ lati gba ọlọpaa, ṣe tọhun le kọwe wa, kẹ ẹ si fun un?
Omooba Adejobi: Ẹ le kọwe wa, ko sẹni to gba bairo lọwọ yin, ẹ kan le ma ri esi gidi gba ni, ọpọ iwe ibeere fun ọlọpaa lo wa lori tabili wa, paapaa bi ẹlomi-in fẹẹ jẹ kansẹlọ lasan, yoo kọwe pe oun naa fẹẹ gba ọlọpaa, bi wọn fi ẹlomi-in jẹ olori ọdẹ laduugbo wọn, oun naa aa kọwe pe oun fẹẹ gba ọlọpaa, iwọ olori ọdẹ ti wọn ni ko o ṣọ awọn eeyan, iwọ naa fẹẹ gba ọlọpaa! Ibẹ ni mo ti ri pe ọpọ eeyan kan gba ọlọpaa lati fi ṣe afẹ aye lasan, a fẹẹ lọ ode ariya, a ko ọlọpaa lẹyin yẹn-yẹn-yẹn. Mo wa lagbo ariya nijọ kan, emi o lọ gẹgẹ bii alukoro ọlọpaa Naijiria, tori ẹ, ko s’ọlọpaa kankan to tẹle mi, lẹni ta a n wi yii ba de tilu-tifọn, lawọn ọlọpaa si n ṣe giri-giri, ti wọn n dalẹ ru, o waa wa gbogbo ẹ sọrun bii ẹni wa loju ogun, mo ni awọn wo leleyii to n ṣe gira-gira yii, ṣe ogun de ni, wọn ni lagbaja kan ni, mo si wo o lọ, mo wo o bọ, ọmọ ti o yẹ ko duro nibi ti awa ba jokoo, awọn ọlọpaa rẹpẹtẹ lo tẹle e. O daa, iṣẹ ki lo n ṣe, wọn lo ti kọwe nigba kan pe ẹmi oun wa ninu ewu, nnkan kan n ṣẹlẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Mo ni iyẹn eleyii naa, ibẹ ni mo ti kọwe pe ki wọn gba ọlọpaa lọwọ ẹ, tori bawọn ọlọpaa ṣe n tẹle e loju agbo gan-an ti emi funra mi loju gẹgẹ bii ọga ọlọpaa. Nigba ti Ọlọrun maa mu un gan-an, ti Eṣu fẹẹ ṣe e, afi “tako tako” (iro ibọn) ti mọ gbọ lori ijokoo, mo ni ki lo bi ibọn to yin, wọn n ki ọga to tẹle wa loju agbo, olorin ki i (mo fi orukọ bo olorin yẹn laṣiiri), ọkan lara awọn olorin wa nilẹ Yoruba ni, olorin n ki i, ewo ni “tako tako”. Mo ni ẹ dakun, ẹyin ọlọpaa tẹ ẹ wa nibi yii, ẹ mu arakunrin yii (ọlọpaa to yinbọn) ẹ ree ti i mọle. Njẹ ẹ mọ pe ọga to tẹle lati Eko wa si agbo ariya, nibi ti agbara gun un de, ko tiẹ waa bẹbẹ fun ẹṣọ ẹ ta a ti mọle pe ‘ẹ jọọ, ẹ ba mi fi i silẹ’, nibi to ni igberaga de, o loun o le bẹbẹ o. Mo ni ki i ṣe ẹbi ẹ, ẹni to fun un ni ọlọpaa ni. A gba ọlọpaa lọwọ ẹ, lati igba yẹn ni ko ti ri ọlọpaa gba mọ. Nibikibi ti awa ta a jẹ ọga ta a ṣẹṣẹ n goke bọ yii ba ti ri nnkan ti ko daa lawujọ, awa n dẹkun ẹ.
Mo si rọ awọn ọga ọlọpaa to n ka ọrọ mi yii, awọn naa yoo ri i pe ohun to tọ lati ṣe ni. ẹ jẹ ka jọ ṣe e, awọn agbalagba sọ pe (o kọrin) ẹ to o mini mini, ẹ ma ma jẹ ko yẹ oo, ẹ to o mini mini, ẹ ma ma jẹ ko yẹ oo, b’agbado ba to’mọ, wọn ko ni i yẹ o. Ẹ jẹ ka jọ ṣe e bi igba ẹkẹ ṣe n dawọ tile, gbogbo awọn ọmọ wa to n ṣe ohun ti ko daa, ẹ jẹ a ba wọn wi, araalu to n ṣe oun ti ko daa, ẹ jẹ a ba a wi, ta a ba fẹ ki ilu da.
ALAROYE: Bawo ni ibalopọ awọn eeyan yin pẹlu araalu ṣe le daa ju bo ṣe wa yii lọ?
Ọmọọba Adejobi: Lori iyẹn, bi ẹyẹ ba ṣe fo la ṣe n sọ’ko ẹ, irini-si ni-sọni lọjọ, bi mo ba wa lori opopona ti mo n dọkọ duro ti mo n ṣe paroolu awọn ọlọpaa kiri, ti mo da ẹ duro, to ba gboju soke, emi naa aa gbe e fun ẹ pada, gba fun Muri ni gba fun Gbada, ti mo ba fi ohun pẹlẹ sọ pe ‘hẹlo,’ ṣugbọn ti iwọ jagbe pada pe ‘yes, yes’, mo tun n ba ọ sọrọ nirona, o waa yi redio soke lala bii pe eeyan kọ lo n ba ẹ sọrọ, họwu, bi eera ba fi’ni pe igi, niṣe la a wọn ọn sọnu. Ẹ jẹ ki awọn ara ilu ma pọn awọn ọlọpaa le, arifin pọ. Aimọye igba ni mo ti wa ninu ọkọ jẹẹjẹ ti mo jokoo lati wo nnkan to n ṣẹlẹ, eyi ta a maa n pe ni social experiment lede oyinbo, ẹlomi-in aa sọrọ sọlọpaa bii pe ki i ṣe eeyan ni. Ọmọ kekere t’Ọlọrun ti ṣẹgi ọla fun, to kan ri owo, Ọlọrun lo mọ’bi to ti ri owo ẹ, to o ba ti de ita, ma jẹ ki owo yẹn gun ẹ de ọdọ awọn agbofinro. Ẹ pọn wọn le, gbogbo ẹnu ni mo fi n sọ ọ yii, tawọn araalu ba pọn ọlọpaa le, awọn ọlọpaa aa pọn wọn le.
Ẹ n gba ọlọpaa leti, ẹ n na ọlọpaa, nilẹ Yoruba, nigba ti aye n j’aye, agbefọba ki i jẹbi. Loootọ, aye ti di aye ọlaju, ṣugbọn ofin ṣi wa. Nigba tawa naa ba ri i pe aṣeju pọ laarin awọn ọmọ wa, a n ba wọn wi. Ọmọ ẹyin mejila pere ni Jesu ni, kan-n-da wa ninu wọn, e waa wo awa to jẹ bii irinwo ẹgbẹrun ọlọpaa la ni, ko sọgbọn ta o ni i ri kan-n-da ninu wọn, ta la fẹẹ fi jọ? Awọn to n ṣe aidaa yii, a n ba wọn wi, araalu gan-an mọ pe a n ba wọn wi, wọn si n kan saara si wa.
Tori isọnu aye la a ṣe n ni ẹgbẹrin ọrẹ, bi irinwo ba yin’ni, irinwo aa si bu’ni. A o le reti pe ki gbogbo eeyan nifẹẹ wa, agbofinro o le lọrẹẹ, tori pe o n gbe ofin ro, niwọnba asiko to n fi n gbe ofin ro yẹn, ko le lọrẹẹ. To o ba jẹ baba ninu ile tabi akọni ti ki i gba igbakugba, to o ba ti de, gbogbo wọn aa sa lọ ni, wọn aa ni ‘aparo jako o, baba buruku yii ti de niyẹn o.’ Awọn ọmọ to o bi niyẹn, wọn n pe ẹ ni baba buruku, tori pe oo gba iwa idọti. Bẹẹ lọrọ agbofinro ṣe ri, aṣa ni, to o ba ti le ri agbofinro, ikoriira a de, o ṣe daadaa o, ko ṣe daadaa o, ikoriira ni.
Awa ta a jẹ alukoro lasan, a o ṣe keesi, a o wadii ẹsun, a o ti-i-yan mọle, a kan n sọrọ lasan ni, wọn fẹẹ bu wa pa, wọn o tiẹ fẹẹ gbọ wa nigba mi-in. Olootọ o si l’ẹni. Awọn ara ilu ni wọn gbọdọ ri i pe awọn fa agbofinro mọra, bẹẹ ba fawọn mọra, agbofinro mi wa to yẹ ko tọ yin sọna, ẹ ma ṣe bayii, tẹ ẹ ba ṣe bayii, ẹwọn ni, ara iṣẹ wa ni ka tọ yin sọna. Amọ awọn ta a fẹẹ tọ sọna ti wọn ti gbe ija ko wa loju, ti wọn maa ri wa lọọọkan, ti wọn aa ti ni erokero, ero odi si wa, bawo la ṣe fẹẹ ṣe e.
Emi maa n sọ fun awọn ọmọ wa, to ba jẹ loootọ lẹ fẹẹ ṣiṣẹ ọlọpaa, tẹ ẹ ba ti duro si titi, ẹ ma ba ẹnikankan sọrọ tabi gba ẹbẹ wọn, nigba tẹ ẹ ba ko eeyan bii igba (200) lọ sile-ẹjọ loni-in, igba lọla, tẹ ẹ ko igba lọ lọtunla lai beere nnkan kan, lai gba kọbọ, wọn aa mọ pe ẹ n ṣiṣẹ. Ọlọpaa to fẹẹ ṣaanu lo n kan iṣoro, oun ni wọn n ko sijangbọn.
Ẹ jẹ ka pọn awọn agbofinro le, ka fọwọ sowọpọ, ka le jọ ni awujọ to wa lalaafia, to nitumọ, a o gbọdọ maa ba a lọ bayii o.