LASTMA ri ibọn ninu ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn mu pe o ṣẹ sofin irinna l’Ekoo

Monisọla Saka

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla ọdun yii, ni Ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, LASTMA, ṣalaye pe awọn mu ọkọ ayọkẹlẹ kan to ṣẹ sofin, awọn si ba ibọn ninu rẹ.

A gbọ pe lasiko ti wọn gba ọkọ ayọkẹlẹ alawọ dudu Honda to ṣẹ sofin eto irinna ipinlẹ Eko, pẹlu bo ṣe n gba ọna ti ki i ṣe tiẹ lagbegbe Ṣangotẹdo, wọ inu Abijo GRA lọ, loju ọna marosẹ Eko si Ẹpẹ, lawọn ri ibọn naa ninu ọkọ tawọn gba lọwọ ọkunrinọhun.

Agbẹnusọ ajọ naa, Taofiq Adebayọ, sọ ninu atẹjade to fi sita pe niṣe ni wọn sare ke si awọn agbofinro ti wọn n ṣiṣẹ pẹlu awọn awọn oṣiṣẹ LASTMA lagbegbe naa.

O ni, “Awọn oṣiṣẹ ajọ LASTMA ri ibọn nla kan ti wọn tọju pamọ sinu ọkọ ayọkẹlẹ Honda alawọ dudu ti ko ti i ni nọmba, lẹyin ti wọn ti kọkọ gba mọto naa lọwọ awakọ ọhun fun wiwa ọkọ nibi ti ko tọ ni wọn ri i’.

Ọga agba LASTMA, Bọlaji Ọreagba, sọ pe awọn ikọ ileeṣẹ naa ti wọn n yide kaakiri ni wọn gba ọkọ ọhun lẹyin ti ọkunrin awakọ naa ta ko ofin eto irinna ipinlẹ Eko pẹlu bo ṣe gba oju ọna tawọn mọto to n dari gba ibomi-in n gba lagbegbe Ṣangotẹdo, lọ sinu Abijo GRA, loju ọna marosẹ Eko si Ẹpẹ.

Ọgbẹni Ọreagba tun sọ siwaju si i pe awọn agbofinro ti wọn n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn LASTMA ti wọn n yide kiri yii ni wọn sare fi ọrọ naa to leti ki wọn le waa ri nnkan kayeefi ti wọn ri ati pe ni kete ti ọkunrin to ni ọkọ ti ko ni nọmba ọhun ṣakiyesi pe wọn ti ri ibọn toun tọju sinu mọto lo fẹsẹ fẹ ẹ. Ko si sẹni to mọ ibi to wọlẹ si.

LASTMA ti fa ibọn ati mọto ti wọn gba naa le ọga ọlọpaa teṣan Ilasan, lọwọ fun iwadii to peye”.

Ọrẹagba waa rọ awọn araalu lati maa kiyesi si ayika wọn, ki wọn si maa ṣe oju lalakan fi i ṣọri, gẹgẹ bi ọdun ṣe n lọ sopin yii.

Leave a Reply