Latari ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an, Baba Ijẹṣa padanu iṣẹ olowo nla

Faith Adebọla, Eko

Adanu n gori ibanujẹ ni lasiko yii fun gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa nni, Ọlanrewaju James Ọlayinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa. Latari ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an, ti wọn si ti tori ẹ sọ ọ sahaamọ ọlọpaa, ileeṣẹ kan to n ṣe aṣoju wọn ti fawe adehun wọn pẹlu rẹ ya, wọn lawọn o fẹẹ laṣoju awọn mọ.

Ba a ṣe gbọ, Ileeṣẹ Matrix Homes and Property Limited, ileeṣe to n ba ni kọle, ta ile, ra ilẹ tabi ilẹ niluu Eko ni, Baba Ijẹṣa si ni aṣoju ileeṣẹ yii, lati ọdun 2019 ni wọn ti yan an ni ambasadọ wọ.

Wọn ni miliọnu mẹẹẹdogun (N15m) lowo ti wọn n san fun un lọdun lati ba wọn polowo, ko si ṣe igbelarugẹ ileeṣẹ ọhun.

Ṣugbọn lọjọ Abamẹta to kọja yii nileeṣẹ naa fi atẹjade pataki kan sita pe awọn o lo Baba Ijẹṣa mọ latari ẹsun ti wọn fi kan an yii, awọn si ti wọgi le iwe adehun tawọn ṣe pẹlu ẹ, ki i ṣe ambasadọ awọn mọ.

Atẹjade naa ka pe: “Ileeṣẹ Matrix Homes and Properties Limited fẹẹ fi to gbogbo awọn onibaara wa atẹyin araalu leti pe Ọgbẹni Omiyinka Ọlanrewaju James ti inagijẹ rẹ n jẹ Baba Ijẹṣa ki i ṣe aṣoju ileeṣẹ wa mọ o, latari iwa aibojumu to hu, eyi to lodi si ilana ati amuyẹ ileeṣẹ wa.

“Latari eyi, ileeṣẹ wa ko ni ohunkohun i ṣe pẹlu Baba Ijẹṣa lati asiko yii lọ.”

Ọpọ eeyan lo ti gboriyin fun awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa fun igbese ti wọn gbe yii. Lori atẹ ayelujara, lawọn ibi ti wọn pin ọrọ ọhun de, niṣe ni wọn n kan saara pe bo ṣe daa niyẹn, wọn niwa ti afurasi ọdaran naa hu to eyi ti wọn fi ni lati le e sọnu nipo aṣoju ileeṣẹ eyikeyii.

Leave a Reply