Latari iku ọlọkada kan, awọn ọdọ fẹhonu han l’Akungba Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Diẹ lo ku ki ọrọ iku ọmọkunrin kan, Shuaibu Haruna, da rogbodiyan silẹ niluu Akungba Akoko lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii pẹlu bi awọn ọdọ kan ṣe jade soju popo lati fẹhonu han ta ko ọna ti wọn gba ṣeku pa ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn naa.

Awọn ọdọ tinu n bi ọhun la gbọ pe wọn ya bo tesan ọlọpaa to wa niluu Akungba, ti wọn si n beere fun yiyọnda afurasi kan tọwọ tẹ lori ọrọ iku ọmọkunrin naa ki wọn le ṣe idajọ fun un lọwọ ara wọn.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe afurasi tọwọ tẹ ọhun, ẹni tawọn eeyan mọ si Paul ni wọn lo lọọ ba Haruna lalẹ ọjọ Isẹgun, Tusidee to kọja, to si bẹ ẹ pe ko sare sin oun de ibi kan.

Ohun to ya awọn eeyan lẹnu ni bi Paul ṣe da nikan pada sile lọjọ naa to si kọ lati sọ fun ẹnikẹni ibi ti ọrẹ rẹ ti wọn jọ jade wọlẹ si.

Lẹyin-o-rẹyin lawọn eeyan hu u gbọ pe Paul sọ fun iyawo rẹ pe o ṣee koun sa kuro niluu laaarọ kutukutu ọjọ keji ti i ṣe Ọjọruu, Wẹsidee, nitori pe awọn ajinigbe ti pa Haruna ọrẹ oun lasiko ti awọn jọ jade.

Kia ni wọn lobinrin naa lọọ fi ohun to gbọ to iya ọkọ rẹ leti, ti awọn mejeeji si jọ mori le agọ ọlọpaa to wa l’Akungba lati fohun ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun wọn.

Ṣọọbu Paul ni wọn lawọn olufẹhonu han naa kọkọ lọ, ti wọn si dana sun un lati oke delẹ, bakan naa ni wọn tun ba gbogbo dukia to jẹ ti iyawo rẹ jẹ ki wọn too gba tesan ọlọpaa, nibi ti wọn ti afurasi ọhun mọ lọ, ti wọn si ni o di dandan ki wọn fa a le awọn lọwọ fun ijiya to yẹ.

Leave a Reply