Lati Ikorodu ni Moses ti waa jale l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogoji kan, Babajide Moses, atawọn meji mi-in ni wọn ti wa nikaawọ awọn ọlọpaa to n gbogun ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun niluu Akurẹ lori ẹsun jiji jẹnẹretọ nla meji gbe.
Awọn afurasi ole ọhun lọwọ tẹ loju ọna marosẹ Akurẹ si Ileṣa, ni nnkan bii aago meje aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja.
Ninu alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, ṣe fun wa nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, o ni ṣe lawọn agbofinro lepa awọn afurasi ọdaran naa titi tọwọ fi tẹ wọn pẹlu ẹrọ amunawa nla meji ti wọn ko sinu ọkọ eyi ti wọn n ko lọ siluu Eko.
Moses ni wọn lo pada jẹwọ fun awọn nigba ti awọn n fọrọ wa a lẹnu wo pe oun gan-an loun lọọ ji awọn jẹnẹretọ lisita mejeeji lawọn ibi kan l’Akurẹ, o ni oun lo bẹ awọn meji yooku lọwẹ lati waa ba a wu ẹrọ amunawa naa nibi ti wọn ri i mọ ti wọn si tun ran an lọwọ lati gbe e lọ s’Ekoo.
Ẹbẹ ni afurasi ọhun n bẹ nigba ta a n fọrọ wa a lẹnu wo, o ni iṣẹ ti ko si lọwọ oun lati bii ọdun meji sẹyin lo sun oun de idi iṣẹ ole jija.
O ni iru jẹnẹretọ bẹẹ meji loun ti ji gbe sẹyin, eyi ti oun ta ọkọọkan wọn ni ẹgbẹrun lọna igba Naira fun onibaara kan to wa lagbegbe Owode, nipinlẹ Eko.
Moses ni ka ba oun bẹ awọn ọlọpaa ki wọn dariji oun, o ni oun bẹ wọn ki wọn fi ohun to ṣẹlẹ naa fa oun leti nitori pe oun ko jẹ tun iru nnkan bẹẹ wo mọ.

Leave a Reply