Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Bi ọjọ igbeyawo awọn oṣere tiata Yoruba meji nni, Lateef Adedimeji ati Bimpe Oyebade, ṣe n sun mọle, ọkọ iyawo, Lateef, ti sọ ọ di mimọ pe latigba tawọn ti sọ ere tawọn n ṣe naa di ootọ, tawọn ti dajọ igbeyawo lawọn ọta ti pọ ju ọrẹ lọ foun atiyawo oun.
Ọsẹ to kọja ni Lateef sọrọ yii fun iwe iroyin oloyinbo, Tribune, ninu ifọrọwerọ ti wọn ṣe fun un. Ọmọkunrin to fẹẹ gbeyawo lọjọ kejilelogun, oṣu kejila yii, ṣalaye pe, “Mo mọ pe lati ọjọ ta a ti pinnu lati gbe ajọṣepọ wa lọ sipele to kan la ti ni ọta to pọ ju ọrẹ lọ, ṣugbọn ko le ṣe ko ma ri bẹẹ, a o dẹ le ṣe nnkan kan si i.
“Nnkan to kan ṣẹlẹ ni pe to ba wu eeyan lati jẹ kiru nnkan bẹẹ daamu ọkan ẹ, ko faaye silẹ fun un, teeyan ba dẹ mọ pe ipakọ o gbọ ṣuti, eeyan aa yaa tẹsiwaju pẹlu ile aye e, ko ni i gbọ tawọn ọta.
“Mo ti ri awọn ti wọn n beere pe ki lo de ti mo fi fẹẹ ṣegbeyawo bayii, wọn ni ki lo n ṣe wa, awọn mi-in n beere pe ṣe a tiẹ mọ ohun ti a fẹẹ kọrun ara wa bọ yii, oriṣiiriṣii ni kaluku wọn n sọ. Ṣugbọn emi o ni ẹjọ ti mo fẹẹ ba ẹnikẹni ro, aye mi ni mo gbaju mọ, pẹlu iṣẹ mi ati ọjọ iwaju mi.”
Nigba to n sọrọ nipa bi oun ati Mo-Bimpe ṣe n rọwọ mu lagbo tiata, Adedimeji sọ pe ki i ṣe mi-mọ ọn ṣe awọn, bi ko ṣe pe aanu lawọn ri gba.
Ọmọ ilu Abẹokuta yii sọ pe loootọ loun n ṣiṣẹ oun bii iṣẹ, ṣugbọn Ọlọrun lo ni gbogbo ogo lori oun ati Mo-Bimpe.